Plateau: Ẹ̀mí 86 ṣ'òfò ni ìkọlù tuntun

ìpínlẹ̀ Plateau Image copyright Chuwang Dalyop
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sòfò ní ìpínlẹ̀ Plateau

Eniyan bii aadọrin ni àwọn alaṣẹ Ipinlẹ̀ Plateau sọ pe wọn ti ku ninu ikọlu awọn darandaran ati awọn agbẹ ni agbegbe Gashish ati Ropp ni Ipinlẹ Plateau.

Ṣugbọn awọn ile iṣẹ iroyin kan ni àwọn to ku to igba eeyan.

Iroyin to n tẹ̀ wa lọwọ fi han pe Ọjọbọ ni ija naa bẹrẹ nibi ti ikọlu kan ti gbẹ̀mi darandaran marun. Sugbọn nigba ti awọn darandaran naa lọ ṣi'gun pada wa ni ọjọ Abamẹta, oku sun lọ ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijọba Ipinlẹ Plateau ti f'ofin gbele-ẹ lọ́lẹ̀ ni àwọn agbegbe ti ikọlu náà ti waye.

Àgbegbe to yi ibi ikọlu naa po bii Barkin Ladi ti n gbona fun bii ọdun mẹwaa bayii nitori ija laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Bii oṣu kẹrin ọdun yii ni ija tun bẹ lẹ l'akọtun.