Ìpànìyàn Plateau: Buhari, Lalong gbanájẹ lórí wàhàlà tó mú ẹ̀mí 86 lọ

Ààrẹ Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Atẹjade kan latọdọ awọn ọlọpa nipinlẹ naa ni eeyan mẹrindinlaadọrun lo ku ninu iṣẹlẹ Plateau

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ibanujẹ nlanla ni ikọlu to waye lawọn ileto kan nipinlẹ Plateau.

Aarẹ Buhari ni o di dandan ki awọn to wa nidi ikọlu naa o jẹ iyan wọn niṣu.

Ni Ọjọ Aiku ni okiki kan pe awọn ija laarin awọn darandaran ati agbẹ ti ran ọpọ eeyan lọ sọrun.

Atẹjade kan latọdọ awọn ọlọpa nipinlẹ naa ni eeyan mẹrindinlaadọrun lo ku ninu iṣẹlẹ naa.

Image copyright @SimonLalong
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọ̀pọ̀ dúkìá bíi alùpùpù, ilé àti ọkọ̀ ló parẹ́ sínú ìjà náà

Bakan naa ni wọn tun ṣalaye pe eeyan mẹfa farapa, wọn dana sun aadọta ile, alupupu marundinlogun ati ọkọ meji ninu ikọlu naa.

Aarẹ Buhari ni gba-gba-gba bayii nijọba apapọ duro ti ijọba ati awọn eeyan ipinlẹ naa ninu irora wọn.

Ibanujẹ ọkan nla ni adanu ẹmi ati dukia to waye ninu ikọlu ipinlẹ Plateau.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro

Mo ba awọn eeyan ileto ti ọrọ kan kẹdun, mo si n fi da wọn loju pe mi o ni sun, mi o si ni wo titi ti awọn apaniyan ati amokunṣika ẹda to wa nidi rẹ yoo fi fi im u ko ata ofin."

Bakan naa, Gomina Simon Bako Lalong ti kede ofin konile o gbele alaago mẹfa irọlẹ si agogo mẹfa idaji lati yanju wahala miran to lee fẹ ṣẹyọ lori ikọlu naa.

Gomina Lalong ni ijọba ipinlẹ Plateau atawọn agbofinro n ṣiṣẹ laisinmi ati lai kaarẹ lati rii pe gbogbo awọn ti wọn wa nidi wahala naa ni wọn yọ sita bi ẹni yọ jiga.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ile iṣẹ iroyin kan ni àwọn to ku to igba ènìyàn

"Igbesẹ ti bẹrẹ lori wiwa ọna ati daabo bo awọn ileto ti ọrọ kan. Ofin Konile o gble naa yoo wa ni ijọba ibilẹ gusu Jos, Riyom ati barkin ladi titi di igba ti a ba kede pe ko duro."

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gbe oku awọn to ku fun awọn ẹbi wọn lati ṣeto ikẹyin to tọ fun wọn.

Ikọlu laarin awọn darandaran ati agbẹ olohun ọsin nipinlẹ Plateau atawọn ipinlẹ kan lagbegbe aringbungbun ariwa ati ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ti n di lemọlemọ ti ọpọlọpọ ẹmi si ti baa lọ.