Ikú ọmọ Dbanj: Ohun ti awọn òṣeré n sọ

Dbanj Image copyright @iambangalee
Àkọlé àwòrán Oṣù tó kọjá ní Daniel pé ọmọ ọdún kàn

Ọ̀fọ̀ ti ṣẹ̀ ní ìdílé gbajúgbajà akọrin tàkasúfèé ọmọ orílèèdè Nàìjíríà, Daniel Oyebanjo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Dbanj.

Dbanj, pàdánù ọmọ rẹ tí orúkọ rẹ n jẹ Daniel ẹni tó pé ọmọ ọdún kan láìpẹ́ yìí.

Image copyright Instagram/iambangalee
Àkọlé àwòrán Oṣù tó kọjá ní Daniel pé ọmọ ọdún kàn

A gbọ́ pé inú adágún omi ti won se lọ́jò sínú ilé wọn ni ọmọ náà já sí ti ó sí kù sí inú rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn ikú ọmọ Dbanj jẹ́ nnkan tí o kò òpó ọmọ orílèèdè Nàìjíríà nínú.

Ikú, bo je t'ọmọdé tàbí àgbà jẹ nnkan tí ó máa ń ba ni nínú jẹ.

Kété ti ìròyìn jáde ní àwọn èèyàn tí n ki Oladapo Daniel Oyebanjo ku ara feraku ọmọ rẹ.

Ruggedy Baba to je ilumoka olorin takasufe wa lara awọn to fi ikini ransẹ.

Banky W naa sọ pe iroyin ọ̀hún fọwọ ba oun lẹmi tohun ti iroyin isẹlẹ ipaniyan to waye ni ipinlẹ Plateau

Olamide ati Davido ko gbẹyin

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAjé kò gbà, ẹ rìn síwájú

Awọn ololufe Dbanj ti n bá a kẹ́dùn láwọn ojú òpó ayélujára tó ní.

Wọn ti gbé òkú ọmọ náà lọ sì ilé ìgbókùúsí kan tó wà ni GRA Ikeja nílu Èkó.

Dbanj wa ni orileede Amerika nibi ayeye idanilola BET.