Banky W: ojoojúmọ́ ayé mi ni mo ti fi lá àlá kó lè wá sí ìmúṣẹ

banky w Image copyright @bankyw
Àkọlé àwòrán Mo mọ pe àwọn eniyan n fẹ aṣoju ọkan wọn

Olorin Takasufe Bankọle Wellington ti kéde loju opo twitter rẹ pe òun ti fẹ mu ìran oṣelu ṣẹ laye oun ni 2019.

Image copyright @bankyw
Àkọlé àwòrán Ifẹ ara agbegbe ti mo n lọ ṣoju fun ló jẹ mi logun

O ni oun mọ pe oun kò ni baba isalẹ ti ọpọ gbà pé o ṣe pataki sí oṣelu Naijiria ṣugbọn oun gbagbọ ninu Ọlọrun.

Image copyright @bankyw
Àkọlé àwòrán Mo ti ṣetan láti ṣoju àwọn eniyan Eti ọsa lAbuja

O sọrọ nipa àwọn nkan bii ọgbọn inú ati ootọ inu ti oun fẹ lo fi dupo aṣojuṣofin fun àwọn eniyan Eti Ọsa nilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTony Elemelu Foundation: Gbogbo okòwò ló ní ìdojúkọ

Banky W. ṣalaye pé oun nigbagbọ ninu agbara oludibo ati ireti awọn eniyan Naijiria lati ni ọjọ iwaju rere ti ko ṣẹyin awọn adari to bẹru Ọlọrun.

O ni o tẹ́ oun lọrun lati gbiyanju wo boya oun a wọle tabi bẹẹ kọ ju ki oun kan fọwọ lẹran lasan lọ lasiko yii.

Banky W. ni Modern Democratic Party ni ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu rẹ, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ẹgbẹ oṣelu ti pari idibo abẹle wọn lati yan oludije ninu idibo 2019 ṣugbọn ajọ eleto idibo INEC ti kede pe aaye ṣi wà fáwọn ẹgbẹ oṣelu lati paarọ àwọn oludije wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionO tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Banky W padanu ọmọ

Image copyright Instagram/iambangalee
Àkọlé àwòrán Ọmọ ọdún kan ní Daniel ọmọ Dbanj tó kù s'omi

Ìkíni ibanikẹdun ko dúró lórí ikú ọmọ Dbanj

Ìròyìn ikú ọmọ Dbanj jẹ́ nnkan tí o kò òpó ọmọ orílèèdè Nàìjíríà nínú.

Ikú, bo je t'ọmọdé tàbí àgbà jẹ nnkan tí ó máa ń ba ni nínú jẹ.

Kété ti ìròyìn jáde ní àwọn èèyàn tí n ki Oladapo Daniel Oyebanjo ku ara feraku ọmọ rẹ.

Ruggedy Baba to je ilumoka olorin takasufe wa lara awọn to fi ikini ransẹ.

Banky W naa sọ pe iroyin ọ̀hún fọwọ ba oun lẹmi tohun ti iroyin isẹlẹ ipaniyan to waye ni ipinlẹ Plateau

Olamide ati Davido ko gbẹyin

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Oshimole: Àwọn aṣáájú APC kò mọ ohun ti wọ́n n ṣe lásìkò yí