Plateau: Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ọlọ́pàá yóò ṣàwárí àwọn amòkùnṣìkà

Ileto kan lẹyin rogbodiyan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn agbebọn ti awọn eeyan funrasi pe wọn jẹ darandaran kọlu ileto meje kan ni agbegbe Barkinladi

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti ran ikọ kogberegbe kan lọ si ipinlẹ Plateau lati lọ gbin eso alafia sawọn agbegbe ti rogbodiyan ti waye laarin awọn darandaran fulani ati agbẹ olohunọsin.

Àkọlé àwòrán Awọn agbebọn ti awọn eeyan funrasi pe wọn jẹ darandaran kọlu ileto meje kan ni agbegbe Barkinladi

Okiki ikọlu laarin awọn darandaran ati agbẹ olohun ọsin kan eleyi ti o ti ṣe okunfa iku eeyan ti ko din ni mẹrindinlaadọrun.

Bakan naa ni ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria tun ṣi ọkan lara awọn igbakeji rẹ to n mojuto ọrọ iṣẹ gbogbo nileeṣẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria lọ si ilu Jos.

  • Ko din ni ẹgbẹrun mẹta ẹmi to ti sọnu sinu ikọlu Darandaran ati agbẹ olohun ọsin ni Naijiria laarin ọdun 2010 si asiko yii gẹgẹ bii ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Human rights watch ṣe fi sita.
  • Ni ọdun 2014 nikan, ko din ni ẹgbẹfa eeyan to ku sinu iṣẹlẹ ikọlu darndarn ati agbẹ olohun ọsin lorilẹede Naijiria.
  • Ko din ni biliọnu mẹrinla dọla ilẹ Amẹrika ti ikọlu Darandaran ati agbẹ olohun ọsin n na ijọba Naijiria lọdun gẹgẹbii ajọ Mercy Corps ṣe fi sita
  • Ni oṣu kinni ọdun 2018 ni ikọlu awọn darandaran ati agbẹ waye ni ilu Bassa nipinlẹ Plateau eyi to ṣokunfa iku eeyan mẹta ati didana sun ogun ile atawọn dukia miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Baluu kekeeke meji, ọkọ ayẹta APC marun, ikọ ọlọpaa kogberegbe mẹta, ikọ agbogun ti iwa igbesunmọmi, CTU meji pẹlu awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni wọn ko lọ si ipinlẹ naa bayii.

Igbagbọ ọpọ ni pe igbesẹ ọga ọlọpaa yii ko ṣẹyin ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari, ninu eyi to ti ṣeleri fun awọn eeyan ipinlẹ Plateau pe igbesẹ abo ati iwadi to tọ yoo waye lori ikọlu naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọlu yii ti n fa ibẹru bojo lori idasilẹ wahala ẹlẹsin jẹsin ati ẹlẹyamẹya ni Plateau.

Awọn agbebọn ti awọn eeyan funrasi pe wọn jẹ darandaran kọlu ileto meje kan ni agbegbe Barkinladi nibi ti wọn ti pa ọpọlọpọ eeyan ti wọn si jo ọpọlọpọ ile ati dukia miran nibẹ.

Iroyin sọ pe ikọlu yii ko ṣẹyin ikọlu kan to ṣiwaju ti wọn ni awọn eeyan kan lọ ṣigun lu awọn darandaran ati ẹran ọsin wọn.

Ikọlu yii ti n fa ibẹru bojo lori idasilẹ wahala ẹlẹsin jẹsin ati ẹlẹyamẹya pẹlu bi pupọ awọn darandaran ti wọn funra ọrọ yii si ṣe jẹ lati ẹya Fulani ati ẹsin musulumi.