Ikú ọmọ D'banj: Àwọn mọ̀lẹ́bí sọ̀rọ̀ lórí ikú ọmọ rẹ̀

Ẹnu ibodè ilé náà
Àkọlé àwòrán Ẹbí D'banj kò fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà

Àwọn ẹbí gbajúgbajà akọrin tàkasúfèé ọmọ orílèèdè Nàìjíríà, Daniel Oyebanjo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Dbanj sọ̀ pé àwọn banujẹ́ gidi gan lórí ikú ọmọ náà.

Ènìyàn kan nínú ẹbí wọn tí kò fẹ́ ká a dárukọ rẹ, sọ pé àwọn kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ tó kan mọ̀lẹ́bí ni.

Ìròyìn fihàn wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lu síta ni nítorí ẹbí sọ wí pé àwọn fẹ́ kí ohun gbogbo wà ní bòńkẹ́lẹ́.

Bákan náà, wọn ní àwọn kò ní dáhùn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kankan lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ní àkókó tí akọ̀ròyìn BBC bẹ agbolé àwọn D'banj wò, kò sí olórin náà nílé bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ohun tó jọ pé ìyàwó rẹ̀ náà wà níbl.

Àkọlé àwòrán Wọ́n ní ògiri ló la ẹnu tí ọ̀rọ̀ náà ṣe lu síta

Kódà bí ẹ bá ṣe ń súnmọ́ agbo ilé gbajúgbajà náà, ìdàkejì gbáà ni afẹ́fẹ́ ibẹ̀ jẹ́ sí bó ṣe ń gbóná níta káàkiri àwọn ẹ̀rọ ayélujára láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.

Ṣe ni gbogbo àdúgbò dákẹ́ rọ́ọ́rọ́ báyìí, bóyá títí di ìgbà tí D'banj náà bá dé.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹbí náà ń gbìyànjú láti má fèsì sí àtẹ̀jáde kankan èyí tó ti ń jà kálẹ̀ láti ìgbà tí ọmọ ọdún kan ọmọ D'banj, Daniel Oyebanji kẹta ti dákẹ́.