SARS: Awọn ará ìlú fi ẹ̀rí síta nípa ìrírí wọn

Àwọn ọlọpàá Image copyright Police/twitter
Àkọlé àwòrán Àwọn tó bá ikọ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ láti ìlú Èkó, Ibadan àti Oshogbo sàlàyé ìrírí wọn lọwọ́ SARS

Láìpẹ́ yìí ní Fídíò kan tó gbilẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára láti fòpin sí àjọ ọlọ́pàá tó wà fún gbígbógun ti ìwà olè (SARS).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS: Awọn ará ìlú fi ẹ̀rí síta nípa ìrírí wọn

Èyí wáyé nípa ìwà ìjẹkujẹ àti ìwà ọ̀daran tí àwọn kọ̀rọ̀wọ̀sí tó wà láàárín wọn ń wù fún ará ìlú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbàti BBC Yorùbá fí ọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ Nàìjíríà tó tí sẹ alábápàdé ẹ̀ka ọlọ́pàá SARS tẹ́lẹ̀ rí ní wọn sàlàyé ǹkan ti ojú wọn ti ri .

Àwọn tó bá ikọ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ láti ìlú Èkó, Ibadan àti Oshogbo sàlàyé ìdojúkọ wọn.

Èyí ní ẹ̀rí tí ẹnìkan fi sọwọ́ sí ilé iṣẹ́ BBC

Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Eri owó ti Lekan Fashakin san fún ọlọpàá

Bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míran gbà pé kìí ṣe gbogbo SARS ní ó ń hùwà ìbàjẹ́ bíkò ṣe àwọn àsáwọ kan tó wà lára wọn, nítorí pé láti ìgbà ti wọn ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ìwà ọ̀daràn tí ń díkù láwùjọ, sùgbọn síbẹ àjọ ọlọ́pàá gbọdọ̀ wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá kí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ láàárin àwọn ọlọ́páà yìí leè tọwọ́ ọmọ wọn bọsọ.