Ìpànìyàn Plateau: Buhari kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ará Plateau

Ìpànìyàn Plateau

Ààrẹ Buhari ti fi ìlú Calabar sílẹ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ Plateau láti mọ ibi tí ǹkan dé dúró àti fún ìbẹ̀wò ìbánikẹ́dún.

Láti ilé ìjọba, ìròyìn tó ni létí wí pé ààrẹ tí ó lọ ṣí iṣẹ́ àkanṣe kan ní Calabar ní ìpínlẹ̀ Cross River ló ti fi ìlú náà sílẹ̀ báyìí.

Lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá sọ pé ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́run ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ Barkin Ladi ní ìpínlẹ̀ Plateau rìn, ọ̀kan lára àwọn tó fara gbá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Ezekiel Danbwarang ti sọ ìtàn bí àwọn darandaran ṣe pa ènìyàn mẹ́jọ nínú ẹbí rẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ nígbà tí ìkọlù bá àwọn darandaran kan tó sì la ẹ̀mí márùún lọ, èyí ló wá koná ìkọlù lsan lọ́sàan ọjọ́ àbámẹ́ta tó tún wá gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Danbwarang sọ fún BBC pé wọ́n pa ìyá, àti bàbá,ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ mẹ́rin, wọ́n sì tún jó ilé wọn pẹ̀lú.

Àkọlé àwòrán,

Plateau state dey north-central Nigeria

"Wọ́n já ilẹ̀kùn ibodè ilé mi wọ́n sì wọ 'yàrá mi wá, níbẹ̀ ni wọ́n ti sọ iná sílé.

Ó ṣì le láti sọ wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù tó lé ní wákàtí mẹ́rin mú kí àwọn darandaran pa ènìyàn tó lé nígba lágbègbè náà.

Oríṣun àwòrán, Chuwang Dalyop

Àkọlé àwòrán,

bí àwọn darandaran ṣe pa ènìyàn mẹ́jọ nínú ẹbí rẹ̀