Ìpànìyàn Plateau: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ènìyàn 13

Plateau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ìpínlẹ̀ Plateau ní ènìyàn 8 nínú ẹbí òun wà nínú awọn 86 to pàdánù ẹmí wọn níbí ìkọlù sí ìlú wọn.

Ọwọ́ sìnkún ọlápàá ti tẹ ènìyàn mẹ́tàlá ní ìpínlẹ̀ Plateau nítorí ìpànìyàn tó gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́rìndíláàdọ́rùn ni Ọjọ Aiku

Agbẹnusọ ikọ ọlọpaa fun ‘Operation Safe Haven’, Major Umar Adam tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC, wi pe àwọn kọ ni ní pẹ́ gbé awọn afurasi naa lọ sí ilé ẹjọ́.

Adam fíi kúu pé àwọn afurasi ti wọn ko jẹ lara àwọn to kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ìhà méjééjì.

Laipẹ yii ni ilé isẹ Ààrẹ Buhari sọ wi pe Buhari yóò sè abẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Plateau láti mọ ibi tí ǹkan dé dúró àti fún ìbẹ̀wò ìbánikẹ́dún.