Dogara: Buhari yóò tún àwọn adarí ẹ́ka ètò àbò tò láìpẹ́

Buhari n bọwọ Bukola Saraki saaju ipade wọn Image copyright Nigeria presidency
Àkọlé àwòrán Ile aṣofin apapọ pẹlu ẹka iṣakoso ti tahun sira wọn lọpọlọpọ igba lori eto abo

Olori ile aṣoju-ṣofin lorilẹede Naijiria, Yakubu Dogara ti ṣalaye pe, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti n gbaradi lati ṣe atunto eto abo rẹ laipẹ.

Dogara ni atunto ọhun wà lati wa ojuutu si rukerudo to n waye lori ọrọ abo lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ti gunlẹ si ipinlẹ Plateau bayii lẹnu abẹwo lori iṣẹlẹ ikọlu naa

Olori ile aṣoju-ṣofin ṣalaye ọrọ yii lẹyin ipade ti awọn olori ile aṣofin apapọ mejeeji, iyẹn Sẹnetọ Bukọla Saraki to jẹ aarẹ ile aṣofin agba ati olori ile aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara ṣe pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori ikọlu to waye ni ipinlẹ plateau lopin ọsẹ to kọja.

" Aarẹ ti gbe awọn igbesẹ to yẹ, ọrọ abo la n sọrọ nipa rẹ yii, kii ṣe awọn ọrọ ti a lee ma tu sita fun araye, ṣugbọn ṣa o ti sọ awọn ohun ti o n ṣe fun wa, atunto to n gbero lati ṣe lati rii daju pe iru rẹ ko ṣẹlẹ mọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Awọn adari lo pe ipade yii lori ọgọrọ ẹmi to ku sinu ikọlu to waye nipinlẹ Plateau ninu eyi ti awọn ọlọpaa ti sọ pe ẹmi to ku ko din ni mẹrindinlaadọrun.

Ẹwẹ, aarẹ ile aṣofin agba orilẹede Naijiria, Bukọla Saraki ti gunlẹ si ipinlẹ Plateau bayii lẹnu abẹwo lori iṣẹlẹ ikọlu naa.