Plateau: Ìgbìmọ̀ àgbà Yoruba pé'pàdé pajáwírì
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Plateau: Àsìkó tó láti fi káádì ìdìbò yanjú ọ̀rọ̀ Buhari

Ìpaniyàn tó wáyé ní Ipínlẹ̀ Plateau ni ọjọ́ Aikú ló jẹ́ àkọrí ìpàdé pajáwírì tí Igbimọ̀ Àgba Yoruba (Yoruba) pè ni Ọjọ́rú.

Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ náà, Ọjọ̀gbọ́n Kunle Olajide, ló bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ l'órúkọ ẹgbẹ́ níbi tí wọ́n ti rọ àwọn ọmọ Naijiria kí wọn gbọn káádì ìdìbò wọn nù nítorí òun nìkan ló lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Wọn ni kadi idibo ni yoo gbọn olori ti ko pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn eniyan rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n ní ó tó gẹ́ẹ́ kijọba ṣe ohun to yẹ lori aabo ara ilu.

Àwọn àwọrán mìíràn níbi ìpàdé náà rèé:

Àkọlé àwòrán Ailaṣọ lọrun paaka, to to apero ọmọ eriwo ni ọrọ eto aabo Naijiria dà bayii.

YCE tún gba àwọn gọminà nímọ́ràn lórí gbígba àwọn darandaran lááyè ní àwọn ìpínlẹ̀ wọn.

Àkọlé àwòrán Ohun a ba jijọ wo, gigun nii gun ni ibi ọrọ dee duro o

Oju àwọn tó gbẹ̀mí awọn olólùfẹ́ OOU rèé

'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Isẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n tó fẹ́ bá akẹ́kọ̀ọ́ lò pọ̀