Iná Edo: Àwọn ọmọ ni àdájọ́ lọ wò ní fásitì, tí ina fi mú wọn

Ọkọ epo kan to jona Image copyright @wololo_co_ke

Bi eeyan ba jẹ ori ahun, yoo sunkun ni ọjọ ẹti nigba ti ijamba ina kan waye ni ilu Ekpoma ni ipinlẹ Edo lasiko ti ọkọ adajọ kan se agbako tanka epo to fọn epo silẹ, to si gbinna.

Adajọ ileẹjọ majisireti Okiti-pupa nipinlẹ Ondo, Banji Ayeomoni pẹlu ọmọkunrin rẹ, Dara ati ibatan wọn kan to fi mọ awakọ la gbọ pe wọn se agbako iku ojiji naa.

Iroyin naa ni isẹlẹ ọhun waye ni agbegbe ti ko jinna si ileekọ fasiti Ambrose Ali ni ilu Ekpoma.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Adajọ Ayeomọni la gbọ pe o lọ wo awọn ọmọ rẹ to wa ni fasiti naa, nigba to si n pada bọ ni isẹlẹ naa waye.

A gbọ pe ipele karun-un eto ẹkọ imọ isegun oyinbo ni fasiti Ambrose Ali to wa ni Ekpoma, ni Dara, ọmọkunrin adajọ to ku naa wa.

Image copyright @SeimenBurum

Ti gbogbo wọn si jẹ Ọlọrun nipe ni ile iwosan kan ti wọn gbe wọn lọ.

Bẹẹ ba gbagbe, igba akọkọ kọ ree ti isẹlẹ tanka epo yoo maa gbẹmi awọn eeyan.

Bakan naa ni irufẹ isl yii waye ni ilu Eko laipẹ yii, eyi to mu ẹmi eeyan mẹsan lọ.

Èèrù ina tó jó ọ̀pọ̀ ọkọ tó sì mú ẹmi lo nilu Eko tí n tútù ṣugbọn àrà àwọn ọmọ Nàìjíríà sí n gbóná lórí ìṣẹlẹ náà.

Lójú òpó Twitter, iriwisi loriṣiiriṣii ní wọn tí n sọ ti ọpọ sí dá lórí pe ki ọkọ epo ma rìn lójú ọsán mọ.

Ìṣẹlẹ náà to waye lagbègbè Ìkóríta Ọ̀tẹ́dọla, Berger, ní opópónà márosẹ̀ Ìbàdàn sí ìlú Èkó lọjobo ní ọpọ èèyàn tí ṣé àpèjúwe rè gẹgẹ bí ìṣẹlẹ tó gbenilọkan soke

Àwọn kàn ní ìjọba kò gbọdọ̀ fí ọwọ yẹpẹrẹ mú ọrọ̀ yí nítorí ìpalára tí àwọn ọkọ èpo àti àjàgbé n ṣé fún ará ìlú kọjá afẹnuso.

Ninu iriwisi tire, Dokita Dipo Awojide ni adura pe ki irufe isẹle bayi ma waye mọ ko le tan ọrọ to wa nile yi bi kò ṣe pe ki ijọba wa wọrokọ fi ṣada lori ipenija ijmaba ina ọkọ agbepo.

Opeyemi Babalola bẹnu ẹtẹ lu bi awọn ohun amaye dẹrun gege bi ọkọ ojurin ati ile ise ipọnpo ko se sisẹ to ni Naijiria.

O ni bi wọn ba n sisẹ ni,ijamba bi ti teko to sẹlẹ ko ba ma waye.

JJ Omojuwa ni asiko ti to bayi ki awọn olori orileede Naijiria se ojuse wọn bo ti se to ati bo ti se ye.

Related Topics