Fredrick Fasheun jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́

Frederick Faseun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Frederick Faseun

Àkọlé àwòrán,

Frederick Faseun di oloogbe

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ba gbogbo ẹya Yoruba kẹdun lori iku Dokita Fredrick Fasheun.

Ibanikẹdun naa jẹ yọ ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki si aarẹ lori ori iroyin Femi Adeshina fi sita lọjọ Abamẹta.

Aarẹ Buhari to ki gbogbo ẹbi oloogbe naa, ṣe iranti ipa ribiribi ti Dokita Fasheun ko ninu ẹgbẹ NADECO , o si gbaa ladura pe ki Edumare dẹlẹ fun.

Ọọni Ifẹ, Gani Adams daro Fasheun

Ọọni ti ilẹ Ifẹ Oba Adeyeye Ogunwusi ti ranṣẹ ibanikẹdun si gbogbo ọmọ Yorùbá lori iku Dokita Fredrick Fasheun , ẹni ti o jade laye ni owurọ ọjọ Abamẹta.

Ọba Ogunwusi ninu atẹjade kan ti oludari eto iroyin rẹ, Moses Olafare fi sita , ṣe apejuwe iku oloogbe naa bi ajalu nla fun gbogbo ọmọ ilẹ kaaarọ oojiire.

O ṣapejuwe Dokita Fasheun bi ọkan gboogi ninun ọmọ Yorubá to fẹran orilẹede Naijiria , to si fi gbogbo ọjọ aye e rẹ ja fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba.

Gẹgẹ bi Ọọni Ifẹ ṣe wi, gbogbo ọmọ Yoruba patapata ni yoo ṣe afẹri bàbá Fasheun.

Oríṣun àwòrán, Faseun

Ẹwẹ, Aarẹ ọna Kakanfo, Oloye Gani Adams naa ti dara pọ mọ gbogbo ọmọ Yoruba lati kẹdun iku Dokita Fasheun to lọ ibi agba a rẹ.

Oloye Adams , to tun jẹ alamojuto apapọ fun OPC, ṣalaye pe ẹni apọle ni baba Fasheun, ẹni ti o ni o jẹ adari rere, to kun fun ọgbọn, imọ ati oye.

Aarẹ ọna kakanfo tun ṣe apejuwe oloogbe naa bi olotiitọ eniyan ati ẹni to jẹ awokọṣe fun gbogbo eniyan.

Oríṣun àwòrán, Fasheun

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ondo ni Dokita Fasheun

Bakan naa, ẹgbẹ ọdọ Yoruba 'Yoruba Youth Socio-cultural Association' ti ba ẹbi, ara, ojulumọ ati gbogbo ọdọ ilẹ Yoruba da aaro agba yoruba to ku.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Olalekan Hammed,sọ ọ di mimọ pe gbogbo akitiyan Oloogbe Fasheun si idagbasoke ọmọniyan jẹ ohun manigbagbe.

Oludasilẹ ẹgbẹ OPC papoda

Olori ẹgbẹ ẹya ọmọ Oodua, Oodua Peopls Congress, OPC Dokita Frederick Fasheun ti jade laye.

Iroyin sọ pe alagba Faṣeun Jade laye ni owurọ ọjọ abamẹta ni ileewosan nla fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH ni Ikẹja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

WORLD AIDS DAY 2018: HIV/ AIDS kìí ṣe ìdájọ́ ikú mọ́

Ni ọjọ iṣẹgun ni wọn gbe e lọ si ileewosan naa fun itọju ki o to jade laye.

Ni ọdun 1938 ni wọn bii ni ilu Ondo, ni ipinlẹ Ondo.

Nigba ti o n fidi iroyin naa mulẹ fun BBC News Yoruba, alamojuto apapọ fun OPC to tun jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Otunba Gani Adams ṣalaye pe lootọ ni Dokita Fasehun ti papoda.