Àwọn agbébọn pa àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́ l'Abuja

Ọlọpa ilẹ Naijiria Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ yòó wáyé

Àwọn agbébọn ṣekupa àwọn ọlọ́pàá ní ìlú Abuja.

Awọn agbebọn naa ni iroyin ni wọn deede yabo awọn ọlọpa naa ni ikorita Galadimawa, loju ọna to lọ si papakọ ọkọ ofurufu to wa ni ilu Abuja.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpa, ẹka ti ilu Abuja, Anjuguri Manzah fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Awọn iṣẹlẹ ikọlu pipa awọn ọlọpa to ti waye laaarin ọdun kan sẹyin

  • Awọn agbebọn kọlu agọ Ọlọpaa kan ni ileto Gegu ni ipinlẹ Kogi, wọn pa ọlọpaa meji lẹnu iṣẹ ni oṣu kẹrin ọdun 2018.
  • Awọn agbebọn pa awọn ọlọpaa mẹta ti wọn n ṣọ ni ibudo ikẹranko pamọ si, gba Zoo nipinlẹ Edo. Loṣu kẹsan ọdun 2017.
  • Awọn agbebọn tun pa ọlọpaa kan ti o n ṣọ ile ọga agba ọlọpaa tẹlẹ, Ibrahim Commasie ni oṣu kẹwa ọdun 2017.
  • Ni oṣu kẹrin ọdun 2018, awọn agbebọn pa awọn ọlọpaa lasiko idigunjale to waye nilu Ọffa.

Àwọn ti iṣẹlẹ naa ṣ'oju wọn ni ẹnu iṣẹ́ ni àwọn ọlọpaa naa wa lasiko ti awọn agbebọn naa dáná ìbọn fun wọn.

Ati pe ni nkan bi aàgo mẹsan alẹ́ ọjọ Ajé ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn, to si tẹ́siwaju fun ọpọlọpọ iṣẹju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀gá ọlọ́pàá kó ikọ̀ kògbéregbè lọ sí Plateau

'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Ara adugbo naa kan to sọrọ ni bo n kẹlẹ ni 'asiko ti awọn ọlọpa da awọn agbebọn naa duro lati ṣe ayẹwo ọkọ wọn, ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn mọ awọn ọlọpa ọhun.

Eyi si ni igba keji laarin wakati mẹrinlelogun ti awọn agbebọn yoo doju ibọn kọ ọlọpaa.