Ilà kíkọ: Adetutu ní ilà tóun kọ̀ ni kò jẹ́ kí òun lọ ilé-ẹ̀kọ́ fásitì

Adetutu Alabi

Oríṣun àwòrán, @adetutuoj8811

Ni igba atijọ, asa ila kikọ jẹ ohun amuyangan ati ara oge sise fun tọkunrin-tobinrin ni ilẹ Yoruba.

Sugbọn o se ni laanu pe asa ila kikọ yii ti wa di ohun itiju nitori ọlaju to de ba wa. Adetutu Alabi jẹ ọkan ninu awọn obinrin ti asa ila kikọ ti ko ba lati ka iwe, pẹlu ọpọ ipa ti ko see sọ miran to tun ni lori rẹ.

Nigba to n salaye loju opo twitter rẹ, @adetutuoj8811, lori ohun ti oju rẹ n ri lawujọ nitori pe o kọ ila, Adetutu ni yẹyẹ, ẹsin ati itiju naa pọ debi gẹẹ, ti oun ko fi lee tẹsiwaju lẹnu ẹkọ oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

"Iwọnba eeyan lo maa ni oye iru irora ti mo n jẹ ati ohun ti mo n la kọja. N jẹ mo sọ fun yin bi wọn se n yẹyẹ mi si titi debi pe mo taku lati lọ sile ẹkọ Yunifasiti? Mo jija gbara, ti mo si ja fita-fita ni ki n to lee ni ominira funra ara mi. Iru eeyan ti mo jẹ ree, ohun ti mo ba foju sun, o gbọdọ tẹ mi lọwọ"

Adetutu ni ẹkọ imọ ofin (law) lo wu oun lati lọ ka ni fasiti, amọ oun ko tilẹ sopo gba fọọmu lati joko se idanwo Jamb, nitori ẹsin ti wọn fi oun se nile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ti to gẹẹ, idi si ree ti oun fi lọ kọ isẹ ọwọ.

"Ẹru n ba mi lati lọ si fasiti nitori yẹyẹ ti wọn maa fi mi se, koda, mo lee pa ara mi ti ẹsin yii ba tun pọ si, idi si ree ti n ko se ba wọn ya fọto nile ẹkọ girama nitori ila ti mo kọ."

Oríṣun àwòrán, @adetutuoj8811

Adetutu fi kun pe, o de asiko kan, ti oun lọ ba awọn obi oun lati mọ idi ti wọn se kọ oun ni ila, amọ alaye wọn ni pe ara asa ilẹ Yoruba ni ila kikọ, eyi ti yoo bu kun ẹwa oun.

O tun sọ siwaju pe ọpọ awọn alejo to ba ri oun ni wọn maa n sọ pe oun burẹwa, toun ba si n rin lọ loju popo nigba miran, awọn eeyan maa n fa oun sẹyin pe oun burẹwa, amọ ti awọn eeyan miran maa n gbeja oun.

Oríṣun àwòrán, @adetutuoj8811

Koda, ila kikọ yii ni Adetutu sọ pe o tun mu ki baba ọmọ oun kọ oun silẹ, nitori pe oju maa n tii lati ba oun rin loju popo.

"Ara idi ti baba ọmọ mi fi kọ mi silẹ ni pe ko fẹ maa fi mi han loju taye. O si ni alẹ ni ki a maa pade. A pade ni ikọkọ fun osu diẹ lọdun 2008, ti mo si loyun lọdun 2009. Obinrin ni mo bi fun-un, ti yoo si pe ọdun mẹsan laipẹ."

Adetutu ni oun ro pe oun ni oun burẹwa julọ ni gbogbo agbaye, toun ko si fẹ ni ajọsepọ pẹlu ọkunrin kankan mọ tori alẹ nikan ni wọn fẹ maa ba oun jade.

Oríṣun àwòrán, @adetutuoj8811

Koda o ni ọkan tiẹ wa, ti oun ba jade fun ọdun meji, gbedeke to si fi lelẹ ni pe alẹ ni awọn yoo maa pade, ti oun si fara daa, toripe ọmọ ọdun mẹrin ni oun wa, ti iya oun fi ku, ajọ alaanu kan si lo wo oun dagba.

Lọwọ-lọwọ bayii, oriire ti gbe alawo re ko Adetutu, ti gbaju-gbaja olorin kan ni ilẹ Amẹrika, Rihanna si ti n fesi pada fun Adetutu lori ibeere rẹ lati ba Rihanna sisẹ pọ.

Ero awọn eeyan nipa ila kikọ

Ohun to kọju s'ẹnikan, ẹyin lo kọ s'ẹlomii ni ọrọ ila kikọ jẹ laaarin awọn ọmọ Yoruba, paapa lode oni.

Bi awọn kan ṣe gbagbọ pe ko si ohun to buru ninu ki obi kọ ila sọmọ loju, ni awọn kan gbagbọ pe aye ti laju kọja ki a maa kọ ọmọ nila.

Àkọlé àwòrán,

Àmì ìdánimọ̀ àti oge ṣíṣe ni ilà jẹ́ nílẹ̀ Yorùbá

Arabinrin Sekinat Adekoge ni 'ohun amuyangan ni ila oju oun jẹ fun oun, lai fi ti eebu ti awọn eniyan maa n bu oun ṣe.

Ni ti Balkiss Yusuph, ila ti wọn kọ sii loju jẹ ki o padanu anfaani lati jẹ akẹkọ to jafafa, nitori pe oju maa n ti i lati dide soke dahun ibeere olukọ, debi wi pe o fẹ rẹ pa ileewe ti.

Àkọlé àwòrán,

Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí pé ó kọlà

O ni 'awọn ẹlẹgbẹ mi fi aye su mi, nigba ti mo wa ni kekere.'

Àkọlé fídíò,

Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Awọn kan ko ri ohun to buru ninu ila kikọ

Ni ero ti @iamtito lori Instagram BBC Yoruba, 'a ko gbọdọ titori pe awọn to kọla n dojukọ idẹyẹsi, ka pa aṣa wa run.'

O ni 'orilẹede Indian ati China ṣi n ṣe amulo awọn aṣa wọn, lai fi ohunkohun ti ẹnikẹni ba sọ ṣe.'

Àkọlé àwòrán,

Kàyéèfì ni ilá maa n jẹ́ fún àwọn tí kì í sẹ ọmọ Yorùbá

Njẹ ofin faaye gba?

Ile aṣofin agba Naijiria ti gbe igbesẹ ri lati fi ofin de ila kikọ lode oni l'orilẹede Naijiria. Ọdun 2017 ni Sẹnetọ Dino Melaye to wa lati ipinlẹ Kogi kọkọ gbe aba ofin naa kalẹ niwaju ile igbimọ aṣofin.

Aba ofin naa n fẹ ki wọn o fi oju ọdaran wo ẹnikẹni to ba kọ ila tabi lọwọ si ila kikọ si oju ọmọde.

Amọṣa, aba naa ko ti i di ofin titi di asiko yii.