Ekiti2018: Ilé ẹjọ́ ni Fayoṣe kò láṣẹ láti f'òfin de Fayẹmi láti dupò òṣèlú

Image copyright Ekiti state government
Àkọlé àwòrán Fayose lo fi aṣẹ ijọba de Fayẹmi la ti maa dije fun ipo oṣelu

Ile ẹjọ giga kan nilu nilu Abuja ti wọgile abajade igbimọ iwadi kan ti ipinlẹ Ekiti gbe kalẹ, eleyi to fi ofin de gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi pe ko lẹtọ lati di ipo ilu mu mọ nipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party, APP lo pe Kayọde Fayẹmi lẹjọ pe ko lẹtọ lati dije nibi idibo sipo gomina ipìnlẹ Ekiti ti yoo waye loṣu yii, nitori iwe aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ekiti gbe jade pe Fayẹmi ko lẹtọ l'abẹ ofin lati di ipo iṣejọba kankan mu nipinlẹ naa.

Ninu idajọ to gbe kalẹ ni ọjọ Iṣẹgun, Onidajọ O.A. Musa ni ipẹjọ ẹgbẹ oṣelu APP ko lẹsẹ nlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oludasilẹ Alibaba, Jack Ma, gbé ìgbésè lórí PVC

'Òṣìṣẹ́ àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n di adigunjalè'

Onidajọ Musa ṣalaye pe Fayẹmi lẹtọ lati dije lasiko ibo gomina ipinlẹ Ekiti to n bọ lọna, nitori idajọ ile ẹjọ to ga julọ l'orilẹede Naijiria lori awọn ẹjọ to jọ iru eyi latẹyin wa ni pe, idajọ igbimọ oluwadi ko lee da ọmọ orilẹede Naijiria kankan duro lati maa lee dije fun idibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, oludari ẹka iroyin nileeṣẹ ipolongo Kayọde Fayẹmi, Ọgbẹni Wọle Olujọbi ni idajọ naa kii ṣe kayefi fun awọn nitori awọn gbagbọ pe gbogbo igbesẹ ti ijọba Gomina Ayọ Fayoṣe gbe lori igbimọ iwadi naa lo ni ọwọ oṣelu ninu, ti ko si fara mọ eto idajọ ododo.

Akitiyan lati kan si igun ijọba ipinlẹ Ekiti lori ọrọ naa ko so eso.