D'Banj: A dúpẹ́ fún ìfẹ́ yín

Aworan Dbanj, iyawo ati ọmọ rẹ Image copyright Instagram/iambangalee
Àkọlé àwòrán Oṣù tó kárùún ọdún ní Daniel pé ọmọ ọdún kàn

Ìlúmọ̀ọ́ká olórin tàkasúfèé ọmọ Nàìjíríà, Ọladapọ Oyebanjọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí D'Banj ti pàpà fọhùn síta nípa ikú ọmọkùnrin rẹ̀.

Bí ẹ bá rántí, D'banj pàdánù ọmọ ọdún kan rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ni ọmọ náà fayé sílẹ̀ tí àwọn ènìyàn sì ń tàn án kálẹ̀ pé inú adágún omi ìgbafẹ́ tó wà nínú ilé D'Banj ni ọmọ náà kú sí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí

Àwọn olórin Nàìjíríà kẹ́dùn ikú ọmọ DBanj

Ẹbí D'banj sọ̀rọ̀ lórí ikú ọmọ ọdún kan rẹ̀

Láti ìgbà náà, ìdílé D'Banj kọ̀ láti bá àwọn oníṣẹ́ ìròyìn sọ̀rọ̀ tábi tẹ ohunkóhun jáde sórí ẹ̀rọ ayélujára.

Nígbàtí akọ̀ròyìn BBC sèbẹ̀wò sí agbo ilé wọn, àti D'Banj, àti ìyàwó rẹ̀, wọn kò kó fìrí ẹnikẹ́ni nínú wọn.

Ẹ̀wẹ̀ lónìí, D'Banj ti fi okun kún okun láti sọ̀rọ̀ jáde sí gbogbo ará ìlú.

Àkọlé àwòrán D'Banj fọhùn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá tí ó pàdánù ọmọ