ÈkìtìElection: Kò sí ayípadà lórí òfin tó de Fayẹmi láti máa leè dipo mú

Fayose Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayẹmi ati Gomina Ayodele Fayoṣe ti wa lẹnu itaporogan fun igba pipẹ.

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti sọ pe ere ọmọde ni idajọ ti ilé-ẹjọ́ giga kan gbe kalẹ ni ilu Abuja ninu eyi to ni iwe aṣẹ ijoba ipinlẹ Ekiti to fofin de Ọmọwe Kayode Fayemi pe ko lee di ipo iṣejọba mu nipinlẹ naa ko fi ẹsẹ mulẹ.Ohun ti ìjọba ipinlẹ Ekiti n sọ bayi ni pe aṣẹ naa ṣi fi idi mulẹ.Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, oluranlowo eto iroyin fun Gomina Ayọdele Fayoṣe, Ọgbẹni Lere Olayinka ṣalaye pe ipẹjọ arumọjẹ lasan ni, atiwipe kosi ẹni to pe ijọba Ekiti to gbe iwe aṣẹ naa kalẹ ni ẹjọ nítorí naa digbi lo duro."O ni yatọ sí ọrọ iwe aṣẹ yii, Ọmọwe Fayemi to n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹjọ lati jẹ ni ile ẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo ipinlẹ Ekiti baṣubaṣu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbimọ oluwadi kan ti ijọba ipinlẹ Ekiti gbe kalẹ lọdun to kọja ti fi idi rẹ mulẹ ninu abajade rẹ pe Kayode Fayemi jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an niwaju rẹ; eleyii to nii ṣe pẹlu ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu.Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ naa o gbe iwe aṣẹ ìjọba jade lori aba ti igbimọ naa gbe kalẹ lati yọ ọwọ Fayemi lawo ipo iṣejọba yowu ni ipinlẹ ọhun.Amọṣa, Fayẹmi ti ṣalaye pe igbimọ pọ ṣe rikiṣi ni ọrọ naa jẹ ati pe bopẹ-boya otitọ yoo fojuhan.Oludari eto iroyin fun ileeṣẹ ipolongo Kayode Fayemi, Ọgbẹni Wọle Olujọbi ni 'awọn eeyan Fayose lo ko si inu igbimọ naa bee, ọmọ ẹgbẹ PDP ni wọn pẹlu, nitorina ko i bi idajọ ododo ṣe lee ti ibẹ jade wa.