Ekiti Votes: Adó Èkìtì sọkutu-wọ̀wọ̀ fún ìpolongo ìbò PDP

Ikorita Olumose ati ero to peju sibẹ
Àkọlé àwòrán Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ekiti ati yika ilẹ wa Naijiria, ni ireti wa pe wọn yoo peju sibi ipolongo ibo naa,

Ilu Ado Ekiti ti n sọ̀kutu-wọ̀wọ̀ fun iwọde ita gbangba fun ipolongo ibo fun oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu PDP, Ọmọwe Kọlapọ Olusọla.

Se ni gbogbo àwọn oju popo to wọ ilu naa kun pitimu fun ero, ti ibudo ipolongo ibo naa, ikorita Ojumose, ko si gba ẹsẹ.

Gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ekiti ati yika ilẹ wa Naijiria, ni ireti wa pe wọn yoo peju sibi ipolongo ibo naa, koda, awọn kan ti fi ikalẹ si ibudo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o ti lẹ jẹ pe eto ipolongo ibo naa ko tii bẹrẹ, sibẹ, n se ara awọn ero to wa nibẹ n wa gale-gale pe ki ayẹyẹ naa bẹrẹ, ti aọn kan ninu wọn si ti n kọrin oselu.

Àkọlé àwòrán Lara awọn eekan ẹgbẹ ti wọn n reti nibi ipolongo ibo naa ni alaga ẹgbẹ oselu PDP ni Naijiria, Uche Secondus

Aago mẹwa aarọ̀ọ ni wọn kede pe ipolongo ibo naa yoo bẹrẹ, amọ o dabi ẹni pe yoo lọ jai diẹ ko to waye.

Lara awọn eekan ẹgbẹ ti wọn n reti nibi ipolongo ibo naa ni alaga ẹgbẹ oselu PDP ni Naijiria, Uche Secondus, awọn gomina PDP, atawọn asaaju ẹgbẹ jakejado Naijiria.