Ìsẹ̀lẹ̀ Ghana: Fífi nkàn ọkùnrin Olùkọ́ seré ni ìbáwí ẹ̀sẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin

Akẹkọ kan ti oju rẹ ko han Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹsun ifipabanilopọ ni wọn yoo fi kan ẹnikẹni to ba ni ibalopọ pẹlu ọmọ ti ko tii to ẹni ọdun mẹrindinlogun ni Ghana

Ajọ to n mojuto eto ẹkọ l'orilẹede Ghana ti da awọn olukọ mẹrin, to n ṣiṣẹ nileewe kan ni ẹkùn Ashanti duro lẹnu isẹ, lẹyin ti wọn fi ipa mu awọn akẹkọbinrin lati fi nkan ọmọkunrin wọn ṣere gẹgẹ bi ibawi.

Dida ti wọn da wọn duro waye lẹyin abọ iwadi igbimọ olubaniwi nileeṣẹ eto ẹkọ ni ẹkùn Ashanti. Igbimọ naa lo ṣe iwadi gbogbo ẹsun hihu iwa ti ko t,ọ ti awọn akẹkọọ fi kan awọn olukọ wọn.

Ni ibẹrẹ ọdun yii, awọn akẹkọbinrin mẹwa nileewe naa, fi ẹsun kan pe awọn kan lara awọn olukọ awọ, n fipa mu awọn lati maa fi nkan ọmọkunrin wọn ṣere titi ti wọn o fi da.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọ̀dé George: Ìpànìyàn ló yẹ ká dẹ́kun, ká tó máa du ààrẹ

Olukọ mẹsan lo farahan niwaju igbimọ naa, ṣugbọn wọn da ọ̀kan silẹ ninu wọn. Diẹ lara awọn akẹkọọ naa tu aṣiri bi ọkan lara awọn olukọ naa ṣe ni ki akẹkọbinrin kan fi ọwọ pa nkan ọmọkunrin rẹ titi to fi da lẹẹmeji ọtọọtọ.