Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti gbé ọlọ́pàá tó pa kọ́pà l'Abuja lọ sílé ẹjọ́

Ọga ọlọpaa Idris Image copyright @PoliceNG
Àkọlé àwòrán Ripẹtọ peters yinbọn pa Angela Igwetu ni ọjọru ọsẹ yii, lalẹ o ku ọla ti yoo pari agunbanirọ rẹ

Iṣẹ ti bọ lọwọ ọlọpaa to yinbọn pa agunbanirọ kan, Angela Igweatu, lọjọru nilu Abuja.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Ripẹtọ Bẹnjamin Peters yoo tun fi oju ba ile ẹjọ.

Kọmiṣọna ọlọpaa nilu Abuja, Sadiq Bello lo ṣalaye ọrọ yii nilu Abuja.

Kọmiṣọna ọlọpaa Sadiq Bello ni 'atimọle ni o wa bayii ni ireti ibẹrẹ igbẹjọ rẹ'.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ko si idi fun Ripẹtọ naa lati yinbọn ati pe awawi ti ọlọpaa naa n ṣe pe agunbanirọ ọhun n pariwo fun iranlọwọ kii ṣe idi fun ibọn yinyin.

O ni awọn ọkunrin meji to wa ninu ọkọ naa sọ pe ile igbafẹ ni awọn ti n bọ pẹlu agunbanirọ to di oloogbe naa ki o to yọ ori sita lati inu ọkọ ati pe ko si ewu kankan to wu ki ọlọpaa naa to yinbọn.

Image copyright IGWETU LINDA NKECHI/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Linda Igwetu ti ọlọpàá yinbọn pa ni Abuja

"Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe igbesẹ gbogbo to yẹ, ọlọpaa ti yinbọn ti wa lahamọ, igbesẹ gbogbo fun ibaniwi ni a si ti pari.

Iṣẹ ti bọ lọwọ rẹ, o si ti farahan niwaju ile ẹjọ. O ti wa latimọle ni ireti igbẹjọ rẹ."

Kọmiṣọna ọlọpaa nilu Abuja ni ileeṣẹ ọlọpaa ko jẹ fi ọwọ pa oṣiṣẹ rẹ to ba tapa si ofin lori nitori gbogbo igba ni wọn n tẹẹ mọ wọn leti pe iwa ọmọluabi ṣe pataki lẹnu iṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLASTMA: Ẹ̀rí la nílò láti fi òsìsẹ́ tó ń gba rìbá jófin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjà ọlọ́pàá àti alápatà ni Bodija gbẹ̀mí Sulia aláìṣẹ̀ ni UCH