MKO Abiọla: Ilẹ̀ ń jèèyàn, kò sẹni ti kò ni kú, ọ̀run nìkan làrèmabọ̀!

Abiola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ohun kan lo so ọpọ awọn eeyan pọ ninu ero wọn nipa Abiọla, iyẹn ni idibo June 12, 1993

Ni ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 1998 ni Oloye MKO Abiola jade laye.

Ọpọ lo mọ Abiola fun oniruuru ohun nigba aye rẹ: fun awọn kan oniṣowo nla ni; fun awọn miran alatilẹyin fun idagbasoke ere idaraya nilẹ Afirika ni bẹẹni fun àwọn miran, olowo ti n fi owo ṣaanu ni.

Amọṣa, ohun kan lo so ọpọ awọn eeyan wọnyii pọ ninu ero wọn nipa Abiọla, iyẹn ni idibo June 12, 1993 eleyi ti gbogbo onwoye gba pe oun lo jawe olubori, ṣugbọn ijọba ologun nigba naa ko gbe ijọba fun un.

Oríṣun àwòrán, @wura_abiola

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ lo mọ Abiola fun oniruuru ohun nigba aye rẹ

Àkọlé fídíò,

Àwọn ará ìlú Abiola ní Abẹokuta bá BBC sọ̀rọ̀

Igbesẹ ati kan an nipa fun ijọba ologun labẹ Ọgagun Sani Abacha lo mu ki Abiọla kede ara rẹ gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Naijiria lagbegbe Ẹ̀pẹ nilu Ibadan eleyi ti o di gbajugbaja gẹgẹ bii ikede ilu Ẹpẹ iyẹn 'Ẹpẹ Declaration'

Eyi lo mu ki wọn gbe e sọ si ahamọ fun ẹsun gbigbimọ ati ditẹ gbajọba ati gbigbe igbesẹ lati da hilahilo silẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @mko_abiola

Àkọlé àwòrán,

Kani MKO Abiola ko tii ku ni, ọdun yii ni ko ba pe ọdun mọkanlelọgọrin

Lẹyin ti Ọgagun Abacha ku ni oṣu kẹfa, ọdun 1998 pẹlu ireti pe Abiọla yoo gba itusilẹ ni iroyin kan seti araye ni ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 1998 pe Oloye Moshood Kashimaawo Olawale Abiola ti jade laye.

Nigba naa, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe ohun mimu tii oyinbo ni oloogbe Abiola mu ti o fi dagbere faye, ṣugbọn ko tii si ẹni to tii fi idi eyi mulẹ.

Ka ni MKO Abiola ko tii ku ni, ọdun yii ni ko ba pe ọdun mọkanlelọgọrin.

Iku Abiọla yii bi ijọngban ati idarudapọ kaakiri ilẹ Yoruba ti ọpọ eniyan n fẹhonu han kaakiri, ti ọpọ ẹmi si ba iṣẹlẹ naa rin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Pọpọ sinsin idibo n lọ lori lawọn wọọdi

Àkọlé fídíò,

'Aláàbọ̀ ara tó ń dari ọkọ̀ ojú pópó ní àìlera kìí ṣàrùn'

Àkọlé fídíò,

LASTMA: Ẹ̀rí la nílò láti fi òsìsẹ́ tó ń gba rìbá jófin

Àkọlé fídíò,

Ìjà ọlọ́pàá àti alápatà ni Bodija gbẹ̀mí Sulia aláìṣẹ̀ ni UCH