Buhari: Ohunkóhun kò le yẹ ìdájọ́ tílé ẹjọ́ dá fún Saraki

Buhari ati Saraki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan Saraki pé ṣe màgò-mágó nígbà tó n kéde dúkìá rẹ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fesi lori idajọ̀ ile ti ile jọ to ga julọ ni Nàìjíríà gbe kalẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Bukọla Saraki.

Buhari ninu atẹjade kan to fisita loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ ni, Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Bukọla Saraki farada ìgbẹ́jọ́ to nira. Ṣugbọn nigbẹhin, o fi idi òdodo ara rẹ mulẹ.

Aarẹ Buhari ṣapejuwe ohun ti Saraki la kọja gẹgẹ bi ohun ti oun fun ra rẹ la kọja nigba mẹta ọtọọtọ to dije fun ipo aarẹ ṣaaju ọdun 2015.

O ni ''wọn yan oun jẹ, oun si lọ sile ẹjọ lẹẹmẹtẹẹta, nitori pe oun ni igbagbọ ninu agbekalẹ ofin. Ati pe ọpẹlọpẹ Ọlọrun ni nkan fi bọ si fun oun ni igba kẹrin.

Buhari ni ohunkohun ko le e yẹ idajọ ti ile ẹjọ naa gbe kalẹ lori ọ̀rọ̀ Saraki, nitori ko si bi ipenija ṣe le pọ to fun ẹka idajọ Naijiria, o jẹ ọkan pataki lara ohun to gbe eto iṣejọba tiwa-n-tiwa ro, ti ẹnikẹni ko si gbọdọ ki ọwọ́ bọ ọ l'oju.

Àkọlé fídíò,

FFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Ajọ to n risi ihuwasi ọmọniyan, CCT, lo fi ẹsun kan Saraki lọdun 2015 pe o parọ́ lasiko to kede dukia rẹ ko to o di aarẹ ile aṣofin agba.

Ọjọ́ Ẹti ni ilé ẹjọ́ to ga julọ ni orilede Naijiria dajọ pe ki Bukọla Saraki maa lọ sile rẹ lalaafia, nitori pe awn ajẹri takoni to wa fun ẹsun ti wọn fi kan ko ni awọn ẹri to pojuowo.