Ọlọ́pàá Ondo: A ó ṣe àfihàn ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat l'Ọjọ́rú

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ondo sọ pé àwọn yóò ṣe àfihàn ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat l'Ọjọ́rú.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa Ipinlé Ondo Femi Joseph sọ pe o ṣeeṣe ki Adeyemi Alao to jẹ ọrẹkunrun khadijat ọmọ Igbakeji Gomina Ipinle Ondo tẹlẹri, Alhaji Lasisi Olubọyọ fẹ lo fun oogun owo.

Alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa naa to ba BBC Yoruba sọrọ wipe ṣe gbe oku Khadijat sinu ile fun ọjọ mẹfa pe fun ifurasi.

Ṣugbọn o fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa yoo duro de ayẹwo awọn dokita ki awọn to le sọ pato ohun to ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Ìtúsílẹ̀ dé f'áwọn ọmọ tó jìn sí kòtò!

Ilé MKO Abiọlá di ibùgbé àwọ̀n asínwín

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ṣajẹ tó gbayì jù láwùjọ

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa yoo ṣe afihan afurasi naa l'Ọjọbọ.

Joseph ni o ti to ọsẹ mẹta ti awọn obi ọmọbinrin naa ti n wa lẹyin to kuro ni ile iwe giga fasiti Adekunle Ajasin University (AAUA) ti o n ti n lo si ile iwe lati lo ki ọrẹkunrin rẹ.