Kí lo kàn ìlànà iyansipo àti ìwé ẹrí NYSC lorílè-èdè Nàìjíríà?

Aworan ile Asofin Naijiria Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ile Asofin agba lagbara lati buwọlu tabi tapa si ẹnikẹni ti Aarẹ ba fi orukọ re sowo si wọn

Kí èèyàn tó gbà isẹ gẹgẹ bí Mínísítà lorílè-èdè Nàìjíríà, o ní àwọn ìlànà kàn tó gbọdọ tẹle.

Lẹ́nu ìgbà tí Nàìjíríà padà sí ìjọba alágbádá, àwọn èèyàn oríṣiríṣi ní àwọn aláṣẹ tí yan láti ṣíṣe pẹlú wọn.

Ṣùgbọ́n kíní òfin sọ nípa ṣíṣe àyẹwò fínífíní fún àwọn tí wọn bá yan sí ipò àti wí pé kí ni ìlànà tí wọn là kalẹ kí èèyàn tó lè di ipò mú ní Nàìjíríà?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCUPP: JJ Ọmọjuwa sọ ohun tí ìdàpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí yóò jẹ́

Àyẹwò ihuwasi ẹni tó fẹ gbà iṣẹ

Abala kéjìlélógóje òfin orílèèdè Naijirià fún Ààrẹ lágbára láti yan èèyàn sípo yálà gẹgẹ bí Mínísítà tàbí fún ipò míràn.

Ṣáájú kí o tó fí orúkọ ẹni náà ránṣẹ, àyẹwò fínífíní yóò tí wáyé lọdọ àwọn ilé ìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ láti mọ irú ẹni tíì ṣe.

Àyẹwò yìí, gẹgẹ bí nnkán tí agbẹjọro Kayode Ajulo sọ fún BBC Yoruba nínú ìfòròwánilénuwò, yóò kàn ''ìwé ẹ̀rí tí ẹni náà n gbé ká àti àyẹwò nnkán ìní rẹ.''

Image copyright FACEBOOK/KAYODE AJULO
Àkọlé àwòrán Labe ofin ko to ki eeyan sise lai ni iwe eri pe ko pari agunbaniro

''Bí oun gbogbo bá dúró ní ṣẹpẹ́, Ààrẹ yóò fí orúkọ ẹni náà ránṣẹ sí ilé aṣòfin àgbà.''

Agbẹjọro Ajulọ ní '' Ìdí tí a fí n ṣé àyẹwò yí ní kí iyansipo yí maba mú àbuku bá Ààrẹ tó yan ẹni náà sìpo.''

Ìwé ẹ̀rí ṣé pàtàkì.

Lára àwọn ìlànà àyẹwò kí èèyàn tó lè di ipò mú ní Nàìjíríà pàápàá jùlọ ipò Mínísítà ni pé o gbọdọ ní ìwé èrí tó péye.

Labẹ òfin Naijiria, o ní oṣuwọn ìwé ẹ̀rí tí èèyàn lè fí di ipò yìí mú.

Image copyright @ngrpresidency
Àkọlé àwòrán Aare a ma yan awọn Minisita lati ba ṣíṣe

Fún ipò Mínísítà, abala mẹ́tàdínláàdọ́jọ sọ pé ẹni bá fẹ di ipò Mínísítà mú ''gbọdọ ní ìwé ẹrí eléyìí tó ṣé dédé òun tí wọn fí n gbà aṣojú ilé aṣòfin àgbà wọlè.''

Nínú ìwé òfin bákan náà, òfin sọ pé èèyàn lè ṣe aṣojú nílé aṣòfin àgbà tó bá tí ní ò kéré tán ìwé ẹrí ileewe gírámà.

Kò sí ìbi tí òfin náà tí sọ wípé èèyàn gbọdọ ní ìwé ikẹkọjáde yunifásítì tàbí ìwé erí pé o sìnrú ìlú labẹ ètò àgùnbánirọ̀ kí o tó lè jẹ aṣojú ilé aṣòfin àgbà.

Ti a bá fí eleyii ṣe oṣuwọn ipò Mínísítà, a jẹ wí pé ìwé erí yunifásítì tàbí ìwé ẹrí kikopa nínú ètò àgùnbánirọ̀ kò ṣe dandan.

Ṣugbọn ọrọ náà gbà àlàyé

Àlàyé akọkọ ti Kayode Ajulo ṣé ní pé ''ẹnikẹni tó bá fẹ ṣé iṣẹ ní Nàìjíríà tí o sí parí ilé ẹkọ gíga yunifásítì tàbí ilé ìwé gbogbo n'isẹ (poly) gbọdọ sìn ìlú fún ọdún kàn. ''

''O se dandan kí o fí ìwé ẹrí isinlu hàn kí o tó lè gbà iṣẹ.''

Image copyright @nysc_ng
Àkọlé àwòrán Ajọ NYSC ko fi ojuure wo awọn to ba n ko lati kopa ninu eto isinlu ọlọdunkan

O tesiwaju pe ''fún iṣẹ aladani àti iṣẹ ìjọba ní òfin yìí wà fún labẹ́ ètò àgùnbánirọ̀. Ko sí sí ẹni ti yóò gbà èèyàn ṣíṣẹ́ tí kò ní bèèrè ìwé ẹrí yìí''.

Alaye ti agbejoro naa se fi han ni ṣoki pe ''bí èèyàn bá sì fẹ ṣiṣẹ́ fún ìjọba yálà gẹgẹ bí Mínísítà ní tàbí ní ipò míràn, bi o bá ti sọ wí pé òun parí ilé ẹkọ gíga yunifásítì, o di dandan kí o fí ìwé ẹrí pé o parí ètò àgùnbánirọ̀ han.''

Èèyàn kò lè di ipò mú ní Nàìjíríà tí o bá fi ìwé ẹrí gbarọgudu ṣọ́wọ́

Àyẹwò fún ẹni tó bá fẹ jẹ Mínísítà ni iwájú ilé aṣòfin àgbà má n n'ise pẹlú àyẹwò ìwé ẹrí ti ẹni náà fi ṣọwọ́ sí ilé.

Ilé a sì máa ṣe àyẹwò ìwé náà pẹ̀lú ìbéèrè lọwọ ẹni to bá fẹ jẹ́ ipò Mínísítà láti mo bóyá o kún ojú oṣuwọn.

Ti o bá dá ilé lójú wí pé ẹni náà kún ojú oṣuwọn ti kò sí ní àlébù kánkan yálà nípa ìwé ẹrí rẹ tàbí ìlera rẹ, ilé yóò buwọ́lù iyansipo rẹ tí yóò sì ní anfààní láti ṣíṣe pẹlú Ààrẹ.