Joseph Hanlon: Ogójì tọ́ọ́nù heroin ló ń gba Mozambique kọjá

Apo ogun oloro Image copyright iStock
Àkọlé àwòrán Pupọ lara ogun oloro to n wọ ilẹ Europe n wa lati Mozambique.

Apo oogun oloro to to ogoji n gba orilẹede Mozambique ni ọdọọdun, Onimọ Joseph Hanlon lo sọ bẹẹ.

Iwadi ti Hanlon lati Mozambique se fihan wipe, orilẹede Mozambique ni orilẹede kẹta ni agbaye, ti wọn ti n gbe oogun oloro kuro lorilẹede naa lo si omiran pẹlu iranwo oju opo ikansiraẹni Whatsapp.

Hanlon ni awọn onifayawọ naa n gbe oogun oloro lati Afghanistan lọ si guusu-iwọ oorun Pakistan, lati ibẹ lọ si ariwa Mozambigue nibi ti wọn ti n gba ọna ẹburu gbe wọ ilẹ Europe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn

Iwadii fihan wipe awọn to n se isẹ fayawọ naa maa n ko o pamọ si inu paali, ti wọn si n lo atẹjisẹ lori ẹrọ ikansiraẹni Whatsapp lati ba ara wọn sọrọ pẹlu orukọ bii 555, Tokapi ati Africa Demand.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede Afghanistan ni wọn ti n gbin ogun oloro, ti wọn a si gbe gba Mozambique lọ si Europe

Onimọ naa fi kun wipe, awọn onibara ma n ra oogun oloro heroin naa ni ọgọọrọ, ti wọn yoo si gbiyanju lati gba a ni orilẹede Mozambique, lẹyin ti wọn ba ti lo Whatsapp lati seto gbogbo nkan ti wọn nilo. Lẹyin naa ni won yoo pin heroin naa ka lo si Olu-ilu South Africa tii Johanesburg.