#EkitiDecides: Fayoṣe fèsì sí ìpolongo ìbò tí Ngige ṣe fún PDP níbi ìpolongo APC

uhari na ọ́wọ́ Kayọde Fayẹmi soke
Àkọlé àwòrán Nibi asekagba ipolongo ibo to waye ni Ọjọ Isẹgun ni ilu Ado Ekiti, ni Chris Ngige ti sìsọ pe kí wọn dá Fayose padà sípò lọ́jọ́ Satide .

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ti dupẹ lọwọ Minisita fun ọ̀rọ̀ awn oṣiṣẹ ati igbani siṣẹ, Chris Ngige fun boṣe polongo ibo fun un.

Lọjọ Iṣẹgun ni Ngige to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nibi asekagba ipolongo ibo to waye ni ilu Ado Ekiti, rọ awọn eniyan ipinlẹ Ekiti lati dibo fun Fayose lẹẹkan si.

Ninu fọnran kan to gba ori ẹrọ ayelujara ni Ngige ti kesi awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati dibo fun ẹni to mọ ọbẹ se julọ bii iyawo l'ọọdẹ ọkọ laarin awọn oludije si ipo gomina, to si ni ki wọn da Fayose pada nitori pe o daju pe oun l;o mọ ọbẹ adidun se.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Ki lo buru ninu keeyan wẹwu agbọta?'

Ṣugbọn ohun to daju ni pe, Gomina Fayose to jẹ ọmọ ẹgbẹ alatako, Peoples Democratic Party kọ lo n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa, bi ko sẹ igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Olusọla Ẹlẹka.

Ninu atẹjade kan ti Fayose fi si oju opo Twitter rẹ lo ti sọ eyi.

Fayoṣe ni ''oun dupẹ lọwọ ọrẹ oun daada, Chris Ngige, fun bo ṣe polongo ibo fun oun nibi ipade ita gbangba gbẹ oṣelu APC to waye ni ilu Ado-Ekiti. O ṣe apejuwe Ngige gẹgẹ bi ẹni ti ki i bẹru lati sọ otitọ

Kin ni awọn araalu n sọ lori ọrọ ti Ngige sọ?

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo si n bi ara wọn leere pe, se asiwi tabi asisọ ni ka pe ọrọ ti Chris Ngige sọ yii, abi o kuku ti ọkan rẹ wa ni, nitori pe, wọn ni o yẹ ki odidi minisita mọ orukọ oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti, labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Kayọde Fayẹmi tọkan-tọkan, ko si yẹ ko maa se asise lati maa fi orukọ rẹ pe ẹlomiran.

Àkọlé àwòrán Erongba araalu ṣọtọọtọ lori nkan ọrọ ti Ngige sọ

Ẹwẹ, AB Ogunbanjọ lori Facebook ni "atọkanwa ni oju teemi, Ngige kọ lo sọ pe ohun o mọ iyatọ laarin Fayose ati Fayẹmi. Ẹma gbagbe pe ẹgbẹ oselu PDP ni Ngige ti lọ si APC.

"Asiri gbogbo won maa to tu. O di igbayen na."