Ekiti Election: Oludije PDP ní ìdigunjalè ọ̀sán gangan tí kò ṣẹlẹ̀ rí ni ìdìbò Ekiti

Eleka
Àkọlé àwòrán,

Emi kọ èsì ìdìbò INEC-Eleka

Elẹka yarí pé irọ́ ni èsì ìdìbò INEC.

Oludije si ipo gomina ni abe ẹgbẹ oselu PDP, Olusọla Eleka ni oun n gba ileẹjọ to n dajọ ọrọ eto idibo ni Naijiria lọ lati koju esi idibo to gbe Kayde Fayemi wọle.

Àkọlé àwòrán,

PDP: Gbogbo ènìyàn mọ̀ pé ipá àti agídí ni APC fi gbà káàdì àwọn oludibo Ekiti

Ẹlẹka ninu atẹjade to fi lede so pe oun ti fi ọwọ osi da esi idibo naa nu nitori pe oun gbagbọ pe oun lo jawe olubori gẹgẹ bi gomina ni ipinlẹ Ekiti.

Bakan naa ni ẹgbẹ oselu PDP ti gbogbogbo fi àtẹ̀jáde síta pé APC ṣe màgòmágó nínú ìdìbò Ekiti.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Kọmísánà fétò ìdìbò ní jàǹdùkú já àpótí gbà ní wọ́ọ́dù mẹ́fà

Kola Ologbodiyan to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic People to fọwọ si atẹjade naa ni akọ okuta ni PDP ti ibo Ekiti ko lee fọ rara.

O ni PDP kọ esi idibo to gbe Fayẹmi wọle patapata nitori pe àjọmọ̀ INEC ati APC atawọn oṣiṣẹ eleto aabo lo bi madaru to ṣẹlẹ l'Ekiti.

Kola ni esi idibo to jẹ ògidì to wa lọwọ PDP lori idibo Ekiti fihan pe Eleka Olusola to dije labẹ PDP lo wọle gegẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti ni eyi to yatọ si ti ajọ INEC.

O ni iwa ipá ni awọn APC atawọn oṣiṣẹ eleto aabo lo fawọn eniyan PDP atawọn ara Ekiti.

PDP fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ tuntun

Kola Ologbodiyan lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni àwọn ti n to gbogbo ẹ̀rí wọn jọ pẹlu gbogbo esi ti awọn oṣiṣẹ PDP ni l'Ekiti papọ .

O ni laipẹ ni wọn yoo fi ẹ̀rí yii gba ipo PDP pada fun Olusola Eleka to yẹ ko wọle idibo naa l'Ekiti.

Kola ni PDP yoo kede igbesẹ ti wọn fẹ gbe lẹyin ti wọn ba pari àtòjọ ẹ̀rí wọn.

Ìwọ́de PDP ṣaaju idibo Ekiti

Ẹgbẹ alatako gboogi lorilẹ-ede yii, PDP, ti n pọnju kẹkẹ si rogbodiyan to waye ni ipinlẹ Ekiti ni ọjọbọ, ti wọn si n kede pe eto iselu wa ni Naijiria n mi lẹsẹ.

Awọn asaaju ẹgbẹ oselu naa, to fi mọ alaga wọn, Uche Secondus to siwaju ifẹhonu han naa, lo lọ si olu ileesẹ ajọ eleto idibo, INEC ati ile asofin apapọ ilẹ wa lati gbe iwe ẹsun wọn kalẹ siwaju awọn asofin naa lori bi ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa se kọlu gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ni ilu Ado-Ekiti.

Àkọlé àwòrán,

Kiko ọpọ ọmọ ogun lọ si tibu-tooro ipinlẹ Ekiti ko ba PDP lara mu

PDP ni aimọye igba ni ijọba aarẹ́ Muhammadu Buhari ti n dun kooko mọ eto isejọba awa ara wa, to si n tubọ̀ fẹju si ni ojoojumọ, paapa ni bayii ti eto idibo gomina ni ipinlẹ Ekiti n sunmọle.

Wọn ni ajọ eleto idibo ilẹ wa ati awọn ileesẹ agbofinro ti yẹsẹ kuro loju opo ofin isẹ wọn, to si ti foju han pe ijọba apapọ ilẹ wa fẹ́ se mago-mago ninu eto idibo naa.

Àkọlé àwòrán,

PDP ni ajọ eleto idibo ilẹ wa ati awọn ileesẹ agbofinro ti yẹsẹ kuro loju opo ofin isẹ wọn,

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

#EkitiDecides: 'Ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ń ṣẹlẹ̀ kìí ṣe ti òṣèlú'

Àkọlé àwòrán,

Ẹsun bi ajọ eleto idibo Inec se n segbe si ibikan ko tẹ PDP lọrun

Awọn koko ẹsun ti ẹgbẹ PDP gbe siwaju ile asofin apapọ ree:

1. Ikọlu ati ọyaju si gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọ Fayose lati ọwọ awọn ọlọpaa, osisẹ ọtẹlẹmuyẹ, awọn ologun ati ẹgbẹlẹgbẹ ọlọpaa kogberegbe.

2. Kiko awọn ẹsọ alaabo kuro lẹyin gomina Fayose saaju ki awọn agbofinro to taku si ẹnu ọna ile ijọba eyi to fidi rẹ mulẹ pe wọn n dete lati gbẹmi Fayose, ti wọn too si ni ibọn seesi baa ni.

3. Kiko ọpọ ọmọ ogun lọ si tibu-tooro ipinlẹ Ekiti pẹlu akọsilẹ to fi han pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn ọlọpaa, ẹgbẹrun marun ọmọ ogun ati ẹgbẹrun mẹrin ati aabọ osisẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn fi sọwọ si ipinlẹ Ekiti.

4> Bi ajọ eleto idibo INEC se n segbe si ibikan- Wọn ni awọn ti hu gbọ pe wọn ti pasẹ fun awọn osisẹ ajọ eleto idibo kọọkan lati ri daju pe oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu APC lo jawe olubori ninu eto idibo naa.

5. Kiko janduku wọ ipinlẹ Ekiti - PDP ni ẹgbẹ-lẹgbẹ awọn janduku lo ti wọ ipinlẹ Ekiti lati awọn ipinlẹ to mule ti wọn bii Ọsun, Ondo ati Kogi, ti wọn yoo si lo wọn lati maa dunkoko mọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti.

6. PDP wa n kesi awujọ agbaye ati awọn ololufẹ ijọba tiwa n tiwa lati gba aarẹ Muhammadu Buahri ni imọran pẹlu ọga agba ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, olori ile isẹ ọmọ ogun atawọn ile isẹ agbofinro yoku, ti yoo kopa ninu eto idibo ni ipinlẹ Ekiti, lati ri pe wọn ka ojulowo ibo tawọn eeyan ba di ni ọjọ Satide.