Ayélujára la fi ń tọpinpin bí wọn se pín ohun èèlò ìdìbò l‘Ékìtì
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ekiti Election: Ìjọba ìbílẹ̀ làwọn òsìsẹ́ Inec yóó sùn mọ́jú ọjọ́ ìbò

Alaga ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji, lasiko to n ba BBC yoruba sọrọ ni, ko si mago-mago kan kan ninu ilana bi ajọ naa se pin ohun eelo idibo sawọn ijọba ibilẹ ni ọjọbọ.

O ni awọn lọga-lọga osisẹ ninu ajọ Inec ati awọn agbofinro lo tẹle awọn ohun eelo idibo naa, to fi mọ awọn asoju ẹgbẹ oselu kọọkan.

O wa fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ekiti balẹ pe, ko ni si ayederu ibo kankan ni ọjọ Satide nitori ori ẹrọ̀ ayelujara ni awọn ti n tọpinpin ọkọ to ko awọn ohun eelo idibo ati ibiti wọn n ja awọn ẹru naa si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: