Ilé ìwòsàn UNN: Lóòótọ́ ọjọ́ ti lọ lórí omi náà, ẹ ma bínú

Alaarẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Chidozie ni ọ̀rá omi mẹ́jọ ni wọ́n fún òun láàrin wákàtí méjìdínlógójì nígbà tí èsì àyẹ̀wò kò tí ì jáde

Akẹkọọ kan to wa ni ipele kẹta ni fasiti Nsukka (UNN), Chidozie Okonkwo ti fẹsun kan ileewe naa pe wọn fa omi t'ọjọ ti lọ lori rẹ si òun lara.

Chidozie to jẹ akẹkọọ imọ ede Gẹẹsi sọ fun BBC pe, iba diẹ lo mu oun toun fi lọ si ileewosan fasiti naa lọjọ karun, oṣu Keje 2018.

O ni ''nise ni wọn tun gba ẹgbẹrun kan aabọ Naira lọwọ oun fun ayẹwo ẹjẹ, lai fi ti pe oun ti san owo eto ilera mọ owo ileewe ṣe.

Igba ti yoo si fi di alẹ ọjọ keji, wọn ti fun Chidozie ni ọpọlọpọ abẹrẹ pẹlu omi mẹjọ, ki esi ayẹwo to ṣe to o jade.

Image copyright @emmyskillful
Àkọlé àwòrán Arabinrin Chidozie sare ya fọto omi naa nigba to ri i pe ọjọ ti lọ lori rẹ

Igba ti ikeji rẹ, Chiamaka wa bẹ ẹ wo nileewosan naa lo ṣakiyesi pe ọjọ ti lọ lori omi ti wọn n fa si ara ikeji rẹ lara.

Oṣu kinni, 2018 ni ọjọ omi naa ti pe. Eyi lo mu ko sare yẹ gbogbo ọra omi ti wọn ti fun tẹlẹ wo, to si jẹ pe bakan naa ni gbogbo wọn ri.

Idi si ree ti aburo Chidozie, Emmanuel se fi awọn aworan omi naa, to fi mọ ile iyagbẹ ileewosan ọhun soju opo Twitter.

Igbakeji ọ̀gá fasiti UNN, Ọjọgbọn Charles Arizechukwu Igwe ti wa ṣẹ kan lẹ pe ko s'ohun to jọ iru iṣẹlẹ bẹ ẹ ni fasiti naa.

O ni "mi o gbọ pe nkan bẹ sẹlẹ, ẹnikẹni ko si wa fi iru ẹjọ bẹ sun wa."

Lootọ ni Chidozie ti n gba itọju nileewosan miran, sugbọn dokita to n tọju rẹ nileewosan tuntun ti wọn gbe e lọ, sọ fun pe akọ iba ati iba jẹdọ-jẹdọ lo n ṣe e. Ati pe omi t'ọjọ ti lọ lori rẹ ti wọn fa si lara ti mu ki kokoro kan, to n ba ile ìtọ̀ jẹ wọ agọ ara rẹ

Titi di asiko yii, ileewosan fasiti UNN ko ti i fun Chidozie ni esi ayẹwo to ṣe. Ṣugbọn wọn ti bẹ Chidozie ati arabinrin rẹ lati maa binu lẹyin ti wọn jẹwọ pe lootọ ni ọjọ ti lọ lori awọn omi ti awọn fa si lara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ará Èkìtì ń fẹ́ gómìnà tí yòò tù wọ́n lára
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: 'Ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ń ṣẹlẹ̀ kìí ṣe ti òṣèlú'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Pọpọ sinsin idibo n lọ lori lawọn wọọdi