Boko Haram: ile ejọ dá ẹ̀wọn ọdún 20 fún Banzana Yusuf

Aga ile nínú yara ìkawe Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ile Ẹkọ Chibok níbi ti ìjínigbé ti wáyé ní ọdún 2014

Ilé ẹjọ́ tí dájọ́ ẹwọn ogún ọdún fún ọdaran míran tó kópa nínú ìjínigbé àwọn ọmọbinrin Chibok.

Banzana Yusuf tó wá láti ìpínlẹ̀ Kano ní wọn sọ sẹwọn nitori pe, ó lọ́wọ́ nínú ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok.

Ọdún merin sẹyín ní àwọn oniṣẹ ibi Boko Haram ji àwọn ọmọdebinrin gbe ni Chibok ni ìpínlẹ̀ Borno.

Wọn ti ri ninu awọn ọmọdebinrin naa ṣugbọn wọn ko tii pé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Òun ní ẹnìkejì tí wọn ti se idajọ fún lẹ́yìn Haruna Yahaya ti wọn dájọ́ ẹwọn ọdún mẹ́ẹ̀dógún fún nínú oṣù kejì ọdún yìí ní ìpínlẹ̀ Niger lẹ́yìn ti wọn jẹ́wọ pe àwọn lọ́wọ́ nínú ìjínigbe náà.

Àwọn ọdaràn méjèèjì yìí wà lára ẹgbẹ́rún kan le ọkandínláàdọ́rinlélẹgbẹta àwọn ọmọ ikọ Boko Haram.

Ó ti di ènìyàn ogójìlénígba ti ìjọba tí sèdájọ fún láti oṣù kẹ̀wá ọdún tó kọjá lóri ìwà ìgbésùmọ̀mí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionStella Akinsọ: Àwọn Ìwé Mímọ́ fi àsẹ sí ìfètòsọ́mọbíbí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ìjọba ìbílẹ̀ làwọn òsìsẹ́ Inec yóó sùn mọ́jú ọjọ́ ìbò
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Sẹgun Adewale ní ìpèsè ohun ìdẹ̀rùn yóò bá ìfẹ́ aráàlú mu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Àwọn ohun èèlò ìdìbò ń dé síjọba ìbílẹ̀