BBC Yoruba ba awọn eeyan kan ni ipinlẹ Ekiti sọrọ lati mọ iru gomina ti wọn fẹ dibo yan.
Ọpọ wọn lo salaye pe awọn n fẹ ki alaafia jọba lasiko ibo naa, ti ko si nii si wahala kankan lẹyin eto idibo naa.
Bakan naa ni wọn ni awọn n fẹ gomina ti yoo maa san owo osu ni oore-koore fun awọn, ẹni ti ko ni maa pa awọn ni ipakupa, ti ebi ko ni pa awọn, ti ọrọ aje awọn yoo si ru gọgọ si.