Ìwádìí BBC: Àwọn ará Èkìtì ń sáré gba N4,000 sáájú ìbò
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ekiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà

iyalẹnu lo jẹ ni ọsan oni nigba ti ikọ iroyin BBC se awari awọn eeyan kan ti wọn n rọ kẹti-kẹti lọ si ile ijọba atijọ to wa ladugbo Okesha ni ilu Ado Ekiti, tii se olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Ninu iwadi ikọ iroyin BBC, a se awari rẹ pe kaadi idibo ni awọn eeyan naa mu dani, ti wọn fi n lọ gba ẹgbẹrun mẹrin naira ẹni kọọkan.