Tọkọ-tayà Osinbajo kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbi Folu Adeboye

Folu Adeboye Image copyright Rccg/twitter
Àkọlé àwòrán O ni àwọn ise ìrànwọ ti ó ń wọn se fawọn ọ̀dọ́ àti àwọn alaini kò lẹ́gbẹ́

Ìyá Adeboye jẹ́ àwòkọ̀ṣe rere fàwọn obínrin ìwòyí

Igbakeji ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo, tí dáwọ̀ọ́ ìdùnnú pẹ̀lú ìyàwó adari ìjọ ìràpada (Redeemed Christian Church of God), Olusọaguntan Folu Adeboye.

Image copyright Osinbajo/twitter
Àkọlé àwòrán Osinbajo dúpẹ́ lọ́wọ́ Mummy G.O, Folu Adeboye bí ó ṣe jẹ àwokọṣe fún àwọn obinrin

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Image copyright Osinbajo/twitter
Àkọlé àwòrán O ni àwọn ise ìrànwọ ti ó ń wọn se fawọn ọ̀dọ́ àti àwọn alaini kò lẹ́gbẹ́.

Osinbajo ní ó jẹ́ ohun ìdunnu lati ni iru arabinrin Folu Adeboye lawujọ àwọn obínrin gẹgẹ bíi oniwàásù àti àwokose fawọn obinrin.

Ó rọ awọn obinrin lati ni suuru pẹ̀lú ẹbí wọn lai faaye gba iwa ipá ninu ile ati lawujọ pẹlu afiwe Iya Adeboye.

O ni àwọn ise ìrànwọ ti Iya Adeboye ń se fawọn ọ̀dọ́ àti àwọn alaini kò lẹ́gbẹ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obinrin jẹ amuludun'

Igbákeji ààrẹ, Ọjọgbọ́n Yemi Osinbajo gbadura kí Ọlọrun túbọ̀ lọ́ra ẹ̀mí wọn

Image copyright Osibajo/twitter
Àkọlé àwòrán O ni àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́ ti ó ń se fawọn ọ̀dọ́ àti àwọn alaini kò lẹ́gbẹ́.

Arabìnrin Folukẹ Adeboye pe ọmọ ààdọrun ọdún lori oke eèpẹ̀ lánàá.

Opọlọpọ eto ni awọn eniyan ṣe lati fi sami ayẹyẹ ọdun rẹ ti awọn èrò pupọ si n ki olukọ ati oniwaasu naa lori ayelujara kaakiri agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Awọn oludibo ko mọ idi ti wọn fi n yin tajutaju ni Okesha
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌbẹ Ẹgusi sise ati jijẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Adebayo: Ẹyin ọ̀dọ́, ẹ káàbọ̀ ságbo ilé Tíátà