Russia 2018: Ọjọ́ 11 ní à ò fí jẹun tí kò rí ibi sùn - Ọmọ Naijiria

Awọn ọmọ Nàìjíríà ní Russia Image copyright Yulia Siluyanova
Àkọlé àwòrán O ní nígbà ti ọ̀rọ̀ náà sẹlẹ̀ obinrin kan tó ń mójú to àwọn ti irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá sẹlẹ̀ sí Yulia Siluyanova ló ti kọ̀kọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú wọn kí ó tó pe òhun.

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ló ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ikọ agbábọ̀ọ̀lù Naijiria ní orílẹ̀-èdè Russia ní wọn kò le padà wále mọ, lẹ́yìn ìdíje ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fìdí rẹmi.

Igbà ènìyàn ló wà ní ilé iṣẹ asojú Nàìjíríà ní Russia nítorípé wọn o rí owó ọkọ̀ léyìn ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2018.

Nígba ti BBC Yoruba ba ọ̀kan lára àwọn ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, ìlé ìṣe àrìrinajó sí ilẹ̀ òkèrè kan to se ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn ní kò ṣe ètò tó péye, tí pápákọ̀ òfurufú sì sọ pé kò sí ǹkan tí àwọn le ṣe síi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

Ọ́ sàlàyé pé nígbà ti àwọn kọ́kọ́ dé bẹ̀, odidi ọja máàrun ni kò fi sí ounjẹ́ tàbí ibùsùn kí aṣójú Naijíríà lórílẹ̀-èdè Russia tó yojú.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Cup: Ambode sanwo ènìyàn 50 ní Russia

O fi kún un pé, ọpẹ́lọpẹ́ Gomina ìpínlẹ̀ Eko Akinwumi Ambode tó wá sí Russia fún àṣekágbà ìdíje ifé ẹ̀yẹ àgbáyé ti 2018 ló síjú àànú wo àwọn ènìyàn lórúkọ ara rẹ̀.

Bákan náà ní BBC Yorùbá tún bá ọmọ Nàìjíríà kan tó fi orílẹ̀-èdè Russia ṣe ibùgbé Kehinde Oluremi sọ̀rọ̀, ó sàlàyé pé Akinwumi Ambode ló sanwó ìrìnà àwọn ènìyàn ààdọ́ta láti pada sílé láàná.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRussia 2018: Awọn alátilẹyin àgbabọọlu kò le pada sílé

O ní nígbà ti ọ̀rọ̀ náà sẹlẹ̀ obinrin kan tó ń mójú to àwọn ti irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá sẹlẹ̀ sí, Yulia Siluyanova ló ti kọ̀kọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú wọn kí ó tó pe òhun.

O ní ilé iṣẹ́ ilè òkèrè kan tí a ò fé dárúkọ ló sètò ìrìnà àlọ àtí ààbọ̀ wọn, sùgbọ́n ti wọ́n yọ owó náà pada kí àwọn tó dé pápákọ̀ òfurufú.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Russia 2018: Awọn alátilẹyin àgbabọọlu kò le pada sílé

Oluremi ní pé ‘Fan IDs’ wọn ló yẹ kí wọn lò, sùgbọ́n ó jẹ́ ohun tó yani lẹ́nu pé kò sí ọnà láti rìn irìnààjò, bótilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ọ̀fẹ́ ní Fan IDs jé láti orílẹ́-èdè Russia.

Olúrẹ̀mi sàlàyé pé àwọn yóò sa gbogbo ipá àwọn látí ríi dájú pé àwọn ènìyàn yìí padà sílé kí Fan ID wọn to parí iṣẹ́ ní Russia

O rọ gbogbo àwọn ẹ́lẹ́yinju àànú ní Nàìjíríà láti ran àwọn ènìyàn yìí lọ́wọ́, nítorí ìtìjú ló jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ìlú onílùú.

Nígbà ti BBC Yorùbá kàn sí ilé iṣẹ́ Turkish Airline ti àwọn ènìyàn ọ̀hún fẹ̀sún kan, aṣojú wọn sàlàyé pé lọ́ọ̀tọ́ ní àwọn èrí to wà níwájú àwọn fí han pé ọks òfurufú àwọn ní wọn bá rin ìrìn àjò, sùgbọ́n àwọn kò tí le fídí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ òṣíṣẹ́ tó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ náa.

Ó ní ìwádìí tí ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọn fi kan, pélú ìdánilójú pé àwọn yóò kan sí BBC padà lẹ́yìn ìwádìí.