Russia 2018: Aare Buhari pase ki wọn lọ ko awọn alátilẹyin àgbabọọlu pada sílé

Russia 2018: Aare Buhari pase ki wọn lọ ko awọn alátilẹyin àgbabọọlu pada sílé

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pasẹ fun Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffery Onyeama lati ko gbogbo awọn to lọ se atilẹyin fun Super Eagles nibi Idije Ife Ẹyẹ Agbaye, Russia 2018 pada wale.

Agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu lo fi lede ni oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.

Laipe yii ni fọnran ati fọtọ jade lori ẹrọ ayelujare to fihan wipe ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ha si Russia lẹyin ti ikọ Super Eagles ja ninu idije naa.

Gomina Ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode lo kọkọ dide iranlọwọ fun awọn eniyan aadọta tọ ha si ibẹ, ti ọpọlọpọ si ti wa to ha si orilẹede Russia.