Russia 2018: Belgium ti gba ípò kẹ̀ta Ife Ẹyẹ Agbaye

àwọn ikọ agbabọ̀ọ̀lù England ati Belgium Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bí England se jà fitafita tó síbẹ̀ wọn ri ipò kẹ́ta mú

England ti fidi rẹmi nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ nígbati wọn wàákò pẹ̀lú Belgium ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ Satide, ní St Petersburg.

Balogun ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Belgium Eden Harzard lo ran ikọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ látim gbégbá orókè, pẹlu bi ìfẹsẹ̀wọ́sẹ̀ náà se parí pẹ̀lú àmi àyò méjì si òdò

Bí England se jà fitafita tó síbẹ̀ wọn ri ipò kẹ́ta mú.

Ọjọ̀ Isinmi ni asekagba Ife Ẹyẹ Agbaye ti Russia 2018 naa yoo waye nigba ti ikọ ilẹ Faransẹ yoo ma a waako pẹlu ikọ orilẹede Croatia.