Ọbasanjọ: PDP bẹ̀bẹ̀ lórí ìwà àìda wọn sí mi

Aworan Obasanjo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán "Ọbasanjọ ti foriji PDP ni ibamu pẹlu ohun ti Bibeli sọ.''

Ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP, ti tọrọ aforiji lọwọ aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lori iwa 'buruku ti wọn hu si.'

Oluranlọwọ fun Ọbasanjọ, Kehinde Akinyẹmi lo fi ikede naa sita fun awọn akọroyin.

O ni alaga apapọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Uche Secondus lo ko igbimọ ẹlẹni mọkanlelogun sodi, lati se abẹwo ikinni si ọdọ Ọbasanjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara ohun ti Secondus tun gbekalẹ nibi ipade naa ni ti iwe adehun ti awọn ẹgbẹ kan fọwọ si, lati da ẹgbẹ oṣelu Coalition of United Political Party, CUPP, silẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alaga apapọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Uche Secondus lo ko igbimọ ẹlẹni mọkanlelogun sodi, lati se abẹwo ikinni si ọdọ Ọbasanjọ.

Ẹwẹ, o ni alaga PDP ọhun tun rawọ ẹbẹ si Ọbasanjọ lati tẹsiwaju ninu wiwa ojuutu si awọn iṣoro to n dojukọ eto ọrọ aje orileede Naijiria.

Akinyẹmi ni, lootọ ni Ọbasanjọ ti foriji wọn ni ibamu pẹlu ohun ti Bibeli sọ, sugbọn ẹgbẹ alajumọṣe African Democratic Congress, ADC, ṣi ni yoo gbe e leke.

Imọran ati itọni Ọbasanjọ se koko lori imurasilẹ PDP fun idibo 2019.

Secondus, to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa fidi rẹ mul pe 'lootọ lawọn oloye ẹgbẹ PDP lọ si Abẹokuta lati ni ijiroro pẹlu ọbasanjọ lori eto idibo ọdun 2019.

O ni ṣiṣe ipade pẹlu ọbasanjọ se koko fun awọn lati gba imọran ati itọni lori imurasilẹ PDP fun idibo 2019.