Ekiti Election: NBC ní EKBC ń gbé ayédèrú èsì ìbò síta

Ami idamọ NBC Image copyright @nbcgovng
Àkọlé àwòrán NBC ni ileesẹ igbohun-safẹfẹ Ekiti n hu awọn iwa to tako ofin isẹ igbohunsafẹfẹ.

Àjọ tó ń se àkóso ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ nílẹ̀ yì, NBC, ti sọ kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ọ̀nà iléesẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Èkìtì .

Ikọ iroyin BBC to wa ni ipinlẹ́ Ekiti ni, ajọ NBC pasẹ pe ki wọn ti ileesẹ igbohun-safẹfẹ naa pa nitori pe o n hu awọn iwa to tako ofin isẹ igbohunsafẹfẹ.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita ni alẹ ọjọ abamẹta ni eyi ti jẹyọ.

Ajọ̀ to n ri si eto igbohunsafẹfẹ lorilẹ-ede Naijiria ni, bi gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose se n kede awọn esi ibo ti ajọ eleto idibo ko fọwọ si, lo mu ki oun gbe igbesẹ naa.

Image copyright @nbcgovng
Àkọlé àwòrán Ajọ̀ NBC ni ileesẹ igbohunsafẹf Ekiti yoo si wa ni titi pa fun igba diẹ na.

Bakan naa ni NBC salaye pe, Fayose tun bọ sori afẹfẹ ileesẹ agbohunsafẹfẹ ipinlẹ Ekiti lati maa sọrọ abuku nipa ajọ eleto idibo ilẹ wa, Inec, ileesẹ ọlọpaa ati awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ.

Ajọ̀ NBC ni ileesẹ igbohunsafẹfẹ Ekiti yoo si wa ni titi pa fun igba diẹ na.