Ekiti Election: Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti pa ìjọba dà lẹ́yìn tí wọ́n kéde Fayẹmi

Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ado-Ekiti yọ àwọn alaga ẹgbẹ́ tó sé ti ìjọba Fayoṣe

Afi bi ere ori itage ni nilu Ado Ekiti to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Ekiti lọjọ Aje, nigba ti ẹgbẹ awọn ọlọkọ èrò yan awọn alásẹ tuntun, eyi to ṣeese ko jẹ ni ibamu pẹlu ayipada to ba eto iṣejọba oloṣelu nipinlẹ naa.

Loorọ kutukutu ni igun kan ninu ẹgbẹ awọn ọlọkada to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, yabo ọpọlọpọ ẹka ile ẹgbẹ wọn lati le awọn alaga ẹgbẹ to wa ni iṣakoso.

Àkọlé àwòrán,

Fayẹmi ti kọkọ jẹ gomina ipinlẹ Ekiti laarin ọdun 2000 si 2014

Kódà wọn yọ àwọn alatilẹyin wọn, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn n ṣe ti iṣakoso Fayose, kuro.

Bakan naa ni ọrọ ri lọdọ ẹgbẹ awọn awakọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọlọ́pà dìgbòlùjà ti lọ sí àwọn agbègbè tí ọ̀rọ̀ kàn

Abẹwo BBC Yoruba si adugbo Old Garage nilu Ado-Ekiti fihan pe ẹgbẹ tuntun to n ṣatilẹyin fun APC ti gbakoso ibudokọ naa, ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti oniroyin BBC ri si n fi pankẹrẹ, waya ina ati orisirisi igi nakan-nakan loju opopona.

Ṣugbọn, wọn ti so okun aabo le lawọn agbegbe ti ọrọ kan, ti awọn ọlọpa digboluja ati awọn ọmọ ologun si wa ni ṣẹpẹ lati pa ina wahala to ba ṣeeṣe ko ṣuyọ.

Saraki ṣe àdúrà fún Fayẹmi

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Bukola Saraki ti fi àtẹ̀jáde síta lójú òpó Twitter láti kí Kayọde Fayẹmi kú oríire ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti.

Saraki sọ pé "O kú oríire Dókítà Kayode Fayemi, Gómìnà tí ìpínlẹ̀ Ekiti ṣẹ̀ yàn lórí àṣeyọrí rẹ nínú ìdìbò gómìnà lánàá. Ọlọrun alágbára yóò tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí o ṣe ń múra láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àkòkò rẹ yóò mú ìdàgbàsókè wá síi fún ìpínlẹ̀ náà àti àgbéga bá ìgbé ayé àwọn ènìyàn".

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

Àwọn Gómínà ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP náà ti bẹ̀rẹ̀ sí kí olùdíje ẹgbẹ́ alátakò, Kayode Fayemi kú àṣeyọrí àbájáde ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti gẹ́gẹ́ bíi gómìnà.

Ẹgbẹ́ PDP sọ wí pé "a fún ẹgbẹ́ wa àti olùdíje wa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kọlapọ Oluṣọla Ẹlẹka ní gbogbo àtìlẹ́yìn tó yẹ láti jáwé olúborí nínú ìdìbò Ekiti sùgbọ́n ó ṣe ni láànú pé a fìdí rẹmi. Nínú ayé, o lè borí, o sì lè kùnà nínú àwọn kan. A kí ajáwé olúborí, Dókítà John Kayode Fayemi kú oríire".

Skip Twitter post, 2

End of Twitter post, 2

Ẹgbẹ́ òṣelú All Progressive Congress ti kí Dókítà Kayode Fayemi tó jẹ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú wọn fún àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ẹgbẹ́ òṣèlú náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé Dókítà Fayẹmi ṣe ìpolongo ìbò tó dá lórí àlàkalẹ̀ rẹ̀ láti ṣe àtúntò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà àti dídá iyì, ìṣedéédé àtìwà ire rẹ̀.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti pé ẹ tú yáyá láti dìbò fún olùdije ẹgbẹ́ wa''.

Ó jẹ́ àfihàn ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí wọ́n ní nínu ipá tí wọ́n ríi pé Kayode Fayemi ni láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣèlérí nínú ìpolongo rẹ̀ àti bí ó ṣe kọ irú òṣèlú tí PDP ń ṣe.

Wọ́n ní ẹ́gbẹ́ àwọn wà ní ipò tó dára láti mú orílẹ̀èdè Nàìjíríà tẹ̀ síwájú.

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Buhari kí Fayẹmi kú oríire

Ààrẹ Muhammadu Buhari naa ti kí Ọmọwé Kayọde Fayẹmi kú oríire fún àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà tí ìpínlẹ̀ Ekiti yàn nínú ìdìbò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé.

Lẹ́yìn ìpolongo ìdìbò ẹgbẹ́ APC, ààrẹ gbóríyìn fún olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC àtàwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ fún iṣẹ́ takun takun tí wọ́n ṣe láti ja àjàyè.

Bákan náà, ààrẹ tún gbóríyìn fún àwọn àwọn ará ìpínlẹ̀ Ekiti pé ìhùwàsí wọn àti àláfíà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi àgbara ìtẹ̀ka wọn láti yan ẹni tí wọ́n fẹ́.

INEC kede Fayemi

Sáájú, ajọ eleto idibo ti kede Kayode Fayẹmi to jẹ oludije fun ipo gomina ni ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ninu idibo gomina ipinlẹ Ekiti.

Alaga ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Idowu Ọlayinka to ṣe ikede naa sọ wi pe Kayode Fayemi bori pẹlu ibo 197,459.

O fidi oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Oluṣọla Ẹlẹka to ni ibo 178,121 janlẹ.

Eyi ni igba keji ti Kayode Fayemi yoo jẹ gomina ipinlẹ Ekiti.

Ẹlẹka jẹ igbakeji gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ, Peter Ayodele Fayoṣe ẹni to fidi Kayode Fayemi rẹmi ninu idibo ọdun 2014 ni ipinlẹ naa.

Skip Twitter post, 3

End of Twitter post, 3

Ajọyọ ni ijọba ibilẹ Fayẹmi

06:37am At'agba at'ọmọde ni ijọba ibilẹ Ọyẹ ti oludije fun ipo gomina ni ẹgbẹ oṣelu APC, Kayọde Fayẹmi ti wa tu sita lowurọ kutu hai fun ajọyọ pe Fayẹmi n jawe olubori ninu idibo naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdọ ijọba ibilẹ Ọyẹ

06:46am Ni afẹmọju kaakiri oniruuru ijọba ibilẹ ati awọn ilu to wa ni ipinlẹ Ekiti, kedere ni oju awọn eniyan da ti wọn si n reti ki ajọ eleto idibo kede abajade esi ibo gomina lati mọ gomina wọn tuntun.

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan ipinlẹ Ekiti nreti esi idibo

'INEC, APC yi ibo'

05:34am Ẹwẹ, awọn alatilẹyin ati aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP to wa ni ile iṣẹ INEC nibi ti wọn ti n ka ibo sọ pe ajọ eleto idibo ti yi ibo da fun ẹgb oṣelu APC. Wọn ni ẹgbẹ oṣelu awọn lo gbe 'gba oroke, ko si ootọ ninu iye ibo ti wọn kede. Nitori naa, wọn n fẹ ki wọn so ikede esi naa rọ titi wọn yoo fi koju iṣẹlẹ to waye ni ijọba ibilẹ Ilejemeje.

Oludije fun ipo gomina nipinlẹ́ Ekiti labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, lo gbegba oroke ninu idibo naa, to si fi ẹyin oludije latinu ẹgbẹ oselu alatako, to sun mọ pẹki-pẹki, Ọjọgbọn Olusọla Ẹlẹka janlẹ̀, ẹni to n soju fun ẹgbẹ́ oselu to n sejọba lọwọ ni ipinlẹ naa, PDP.

Ẹgbẹ oselu APC ni apapọ ibo to jẹ 197,459 nigbati PDP ni 178,115.

Ìbò 19,344 ni APC fi f'àgbà han PDP. Ijọba ibilẹ marun-un ni ẹgbẹ oselu PDP ti jawe olubori nigbati APC moke ninu ijọba ibilẹ mọkanla.

Bi o tilẹ jẹ pe eto idibo naa lọ ni wọọrọ wọ, sibẹ Kọmisana feto idibo nipinlẹ Ekiti fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku kan si ja apoti ibo gba ni awọn agọ idibo bii marun si mẹfa lasiko eto idibo naa.

Esi ibo gomina ni ipinlẹ Ekiti lati ijọba ibilẹ kọọkan:

1) Ijọba ibilẹ Ìlejeméje:

APC - 4,153, PDP- 3,937

2) Ijọba ibilẹ Osí:

APC - 12,342, PDP - 11,145

3) Ijọ̀ba ibilẹ Ifẹlodun/Irẹpọdun:

APC- 13,869, PDP- 11,456

4) Ijọba ibilẹ Ọyẹ́:

APC - 14,995, PDP - 11,271

5) Ijọba ibilẹ Ẹ́fọ̀n:

APC - 5,028, PDP - 5,192

6) Ijọba ibilẹ Mòbà:

APC - 11,837, PDP - 8,520

7) Ijọba ibilẹ Ìjerò:

APC - 14,192, PDP - 11,077

8) Ijọba ibilẹ Gbọnyin:

APC - 11,498, PDP - 8,027

9) Ijọba ibilẹ Emùré:

APC - 7,048, PDP - 7,121

10) Ijọba ibilẹ Ìkẹ́rẹ́:

APC - 11,515, PDP - 17,183

11) Ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti:

APC - 12,648, PDP - 10,137

12) Ijọba ibilẹ Ìkọ̀lé:

APC - 14,522, PDP - 13,961

13) Ijọba ibilẹ Isẹ/Ọrun:

APC - 11,908, PDP - 6,297

14) Ijọba ibilẹ ila oorun Ekiti:

APC - 12,778, PDP - 11,564

15) Ijọba ibilẹ iwọ oorun Guusu Ekiti:

APC - 11,015, PDP 8,423

16) Ijọba ibilẹ Ado:

APC - 28,111, PDP - 32,810