Ekiti Election: Fayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà tí Ekiti yàn

Àkọlé fídíò,

Fayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀ ní kété tó di gómìnà Ekiti

Ní kété ti àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti kéde Kayọde Fayẹmi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Fayẹmi ti fi ọrọ ìdúpẹ̀ ránṣẹ́ síta sí gbogbo àwọn tó jẹ́ kí ìdìbò náà lọní ìrọwọ́rọsẹ̀.

Kayọde Fayẹmi jẹ́ kó dí mímọ̀ wí pé bí wọn ṣe lérò rẹ̀ náà ni ó ṣe rí.

Ìdùnú ṣubú l'ayọ̀ ní Ishan Ekiti, ìlú olùdíje fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC John Kayode Fayemi nínú ìbò Gómìnà ipínlẹ̀ Ekiti.

Kété tí àjọ elétò ìdìbò INEC kéde iròyìn àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìdíje ọ̀hún ni àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní jó tí wọ́n sì ń kọrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Pọpọ sinsin idibo n lọ lori lawọn wọọdi

Nínú ilé rẹ̀ níbi tí òun àti àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti jọ wo ìkéde náà lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì, n'íṣe ni àyọ̀ wọn kún.

Nígbàtí ó n bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Fáyẹmí ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ekiti ló ní àṣeyọrí yìí."Mo fẹ́ fi dá a yín lójú pé gbogbo ohun tí a mọ̀ ìpínlẹ̀ Ekiti fún gẹ́gẹ́ bíi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti àláfáà ni a ṣe tán láti mú padà wá."

Fáyẹmí dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará ìlú, àgbààgbà ẹgbẹ APC àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀.

Àkọlé àwòrán,

Fayemi saaju ikede

Nínú ọrọ tirẹ, gómìnà Ibikunle Amosun ti ìpínlẹ̀ Ògùn ní ìdìbò yìí ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ tí àwọn ará ìlú ní nínú ẹgbẹ́ APC. Ó ní pẹ̀lú ìjáwé olúborí yìí, ẹgbẹ́ náà ti wá fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àwon ìpínlẹ̀ tó wà ní Gúúsù ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi náà bá Kayode Fayemi yọ̀ lórí àbájáde èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti.