Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti fẹ́ pa ìjọba dà lẹ́yìn tí Fayẹmi di gómìnà

Ẹgbẹ́ NURTW n ja l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook

Àkọlé àwòrán,

'Níṣe ni wọ́n fọ́n sí àárin ìlú, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni fi oríṣiríṣi nkan ìjà olóró bá ara wọn jà.'

Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́ sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀, NURTW, ní ìpínlẹ̀ Ekiti, n da ìgboro ru.

A gbọ́ pe níṣe ni wọ́n fọ́n sí àárin ìlú, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni fi oríṣiríṣi nkan ìjà olóró bá ara wọn jà.

Ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣojú rẹ̀, Adeyẹye Ishọla, sọ fún BBC Yoruba pé àwọn kan lára ọmọ ẹgbẹ́ NURTW ọ̀hún ló fẹ́ yọ alága ẹgbẹ́ wọn tó ti wà nípò láti àsìkò ìṣàkóso gómìnà Ayọdele Fayose, tí àwọn alátìlẹyìn ti ẹ̀ nàá sì gbáná wojú wọn.

''Níṣe ni wọn kún gbogbo àárin ojú ọ̀nà, tí ẹnikẹ́ni kò si le kọjá. Ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ, ó dilé.''

" Mo ri i tí wọ́n n dáná sun àwọn ṣọ́ọ̀bù kékèéké tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ojú pópó. Bákan nàá ni ipá àwọn ọlọ́pàá kò ká wọn, àyàfi ìgbà tí wọ́n tó ò kó àwọn ọlọ́pàá adìgbòlùjà, MOPOL, wá ni nkan ṣẹ̀ṣẹ̀ n rọlẹ̀."

Ní bàyíì, wọ́n ti n dá àwọn ọ̀kọ̀ tó n wọ inú ìlú Ado-Ekiti, láti àwọn ìlú mi i padà, kí wọ́n máà bà fi ara gbọta."

"Àwọn ọlọ́pàá mú ẹnìkan níṣojú mi, mí ò si le sọ bóyá ẹnikẹ́ni fi ara pa."

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ NURTW n ja l'Ekiti

Nígbà tí a kàn sí iléèṣẹ́ ọlọ́pàá, alukoro iléèṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Caleb Ikechukwu, sọ pé lóòtọ́ ni òun gbọ́ pé rògbòdìyàn wáyé láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀, ṣùgbọ́n òun kò ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa rẹ̀.

Ṣùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ ti ẹ̀, akọ̀wé ìkéde fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti, Yinka Oyebọde, sọ fún BBC Yoruba pé, lóòtọ́ ni wàhálà nàá wáyé láàrin àwọn tó fẹ́ yọ alága ẹgbẹ́ NURTW.

Àmọ́, ìjọba ti dási i, tí àwọn aláṣẹ sì ti n bá igun méjèéjì ṣèpàdé láti yanjú àáwọ̀ nàá.

Ṣùgbọ́n, ìjà nàá ṣì n lọ lọ́wọ́ ní àsìkò tí a kó ìròyìn yíì jọ.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyíì tí irú ìjà bẹ̀ ẹ́ yóò wáyé

Afi bi ere ori itage ni nilu Ado ekiti to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Ekiti lọjọ Aje, nigba ti ẹgbẹ awọn ọlọkọ eero yan awọn alásẹ tuntun, eyi to ṣeese ko jẹ ni ibamu pẹlu ayipada to ba eto iṣejọba oloṣelu nipinlẹ naa.

Loorọ kutukutu ni igun kan ninu ẹgbẹ awọn ọlọkada to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, yabo ọpọlọpọ ẹka ile ẹgbẹ wọn lati le awọn alaga ẹgbẹ to wa ni iṣakoso, to fi mọ awọn alatilẹyin wọn, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn n ṣe ti iṣakoso Fayose, kuro.

Bakan naa ni ọrọ ri lọdọ ẹgbẹ awọn awakọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọlọ́pà dìgbòlùjà ti lọ sí àwọn agbègbè tí ọ̀rọ̀ kàn

Abẹwo BBC Yoruba si adugbo Old Garage nilu Ado-Ekiti fihan pe ẹgbẹ tuntun to n ṣatilẹyin fun APC ti gbakoso ibudokọ naa, ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti oniroyin BBC ri si n fi pankẹrẹ, waya ina ati orisirisi igi nakan-nakan loju opopona.

Ṣugbọn, wọn ti so okun aabo le lawọn agbegbe ti ọrọ kan, ti awọn ọlọpa digboluja ati awọn ọmọ ologun si wa ni ṣẹpẹ lati pa ina wahala to ba ṣeeṣe ko ṣuyọ.

Àkọlé fídíò,

Operation Velvet: Ilé ẹjọ́ alágbéèká bẹ̀rẹ̀ láti fìyà jẹ́ awakọ̀ tó bá r'úfin

Àkọlé fídíò,

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi