Iléesẹ́ ológun: Àwọn ọmọ-ogun ṣi wá gbọ́ lórí ìsípò-rọpò wọn ni

Ọmọogun Nàìjíríà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Boko Haram: Awọn ọmọogun ò sọnu, enikan péré ló farapa

Àláfíà ti gbàjọba ní pápákọ̀ òfurufú táwọn ọmọogun orílẹ̀ gbà lánàá, láti fẹhonu han lóri bí wọn se pín wọn sí ibùdó tuntun fún iṣẹ́ wọn.

Igbákejì adarí alukoro fún àjọ ọmọogun ilẹ̀ 'Operation Lafiya Dole', Onyema Nwachukwu, ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹjade kan pé, àwọn ọmọogun wọde ìfẹ̀honú hàn, sí bí ileesẹ ologun ṣe pín wọn fun iṣẹ́ ní Maoduguri, èyí dàbí ohun ti kò tẹ́ wọn lọ́rùn tó tó sì fa awuyewuye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá Darasimi: Ọlọ́run fi ìbejì rẹ̀ mí lẹ́kún, lẹ́yìn ikú Darasimi tó mu sódà

O ní àtúnpín àwọn ọmọogun yìí ṣe pàtàkì látàrí àbájáde ìwádìí ètò ààbò ní Maiduguri, sùgbọn o ṣe ni láànú pé, àwọn ọmọogun kan ṣi ọ̀rọ̀ náà gbọ́ ti wọn si bọ́ síta láti fẹ̀hónú hàn nípa yinyin ìbọn ní pápákọ̀ òfurufu nítorí wọn si ọ̀rọ̀ náà gbọ́.

Ẹ̀wẹ̀, o ní àláífìà ti jọba báyìí sùgbọn àjọ ọmọogun kábàmọ pé irú ǹkan bẹẹ waye bí o ṣe kó ìpayà bá àwọn ará ìlú ní pápákọ̀ òfurufú.

Image copyright @HQNigerianArmy

sẹlẹ yii lo mu ki awọn arinrin ajo Hajj to wa ni papakọ ofurufu naa, to fẹ wọ baalu lọ si Saudi Arabia, tete sa asala fun ẹmi wọn.

Boko Haram: Awọn ọmọogun ò sọnu, enikan péré ló farapa

Ilé iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀ tí kédé pé ìròyìn tó gbòde kan pé àwọn ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pòórá ní ìjọba ìbìlẹ̀ Bama ní ìpínlẹ̀ Borno.

Ọmọogun orí ilẹ̀ sọ fun gbogbo ayé pé òtu bántẹ́ ní ìròyìn náà, òtítọ́ kan kò sí níbẹ̀, nítorí náà kí gbogbo èniyàn lọ fi ọkan balẹ̀ pàápàá júlọ àwọn to wà ní ìhà ìlà-oorùn - àríwá láti ketí ọ̀gbọin sí àhesọ ọ̀rọ̀ náà nítori pe ètò ààbò tó wà nílẹ̀ kò ni kọ́nukọ́họ nínú.

Nínú àtẹ̀jáde tó tọwọ́, tó jẹ́ adari alukoro fún ilé iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀, Texas Chukwu jáde sàlàyé pé lóòtọ́ ní àwọn ọmọogun ní ìdojúkọ Haram ní ìlú Chingori ní àgbègbè Bámá nípìnlẹ̀ Borno, tí wọn sì gbìyanjú láti gba mọ́tò sùgbọ́n àwọn ọmọogun ṣì dóju ìjà kọ wọn pẹ̀lú àṣeyọrí àti ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọogun ojú ofurufu Nàìjíríà.

Ó lé ní méjìlélógun nínú àwọn ìkọ̀ Boko-Haram ti wọn sọ di aláìlágbára nígbà ti ọ̀pọ̀ wọn sá lọ pẹ̀lú àpá ọta ìbọn, tí àwọn ọmọogun sì ń sapá láti rí àwọn ọmọ Boko Haram, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọogun kan sì ní àpá ìbọn sùgbọn ó ti wà ní ilé ìwòsàn ọmọogun tó ti ń gba ìtójú.