Ìlérí Fayemi lati san owó oṣù oṣìṣẹ́ l'Ekiti: ẹnu lásán kò lè ṣe é

Fayẹmi ati iye owó to n wọle l'Ekiti
Àkọlé àwòrán,

Odu ni Kayode Fayemi jẹ nidi iṣejoba ṣugbọn nnkan yato lasiko to pada wa yi

Àáyá bẹ sílẹ̀, ó bẹ́ sí aré ní Kayode Fayemi fẹ fí ipadabọ rẹ sì orí aleefa gẹgẹ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣé.

Láì tíì ṣe ibura wolẹ́ sí ilé ìjọba, o ti n pinnu láti sàn owó oṣù oṣiṣẹ láàrín oṣù mẹfa.

Ọ ni bi ìṣẹ́ òun òṣì ti peleke láàrin àwọn ará ìlú ko ṣẹyin bí ìjọba Fayoṣe tí kùnà láti san owó oṣù àwọn oṣiṣẹ.

Ìkéde yí jé òun ti o mú àriwisi otooto wà láàrin àwọn ará ìlú àti àwọn amòye.

Nínú èsì tí rè, Ọgbẹni Kola Bankole to je onimo nipa eto inawo so pe òun tó dáa ní kí ìjọba san owó ní kété ti oṣù bá parí fún àwọn oṣiṣẹ ṣugbọn ọ ti ya ju bi Fáyẹmí ti ṣe n ṣé ìlérí yí.

''Ko ti mò ipò tí akoto owó ijoba ipinle wa, bawo lo ti se fe san owo nigba ti ko ti mo awọn gbese to wa ni ile ati iye owo ti o''n wole fun ijoba ipinle ohun?''

Àkọlé àwòrán,

Àwọn olóṣèlú a má ṣé ìlérí tí wọn kò ní lè mú ṣẹ fún ará ìlú lọpọ ìgbà

Ọgbẹni Kola ní lootọ ni pé Fáyẹmí tí je Gómìnà nígbà kan rí ṣugbọn bí nnkan ti ṣe n ló lẹnu ọjọ mẹta yí tí owó tó yẹ kí ìjọba àpapọ pin fun àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ kò ti ni iyanju, yóò ṣòro kí Fáyẹmí le mú irú ìlérí bẹẹ ṣé.

''O kàn n sọ ọrọ òṣèlú ní. Sisan owo oṣù kọja afẹnuso. O gbọdọ ṣe àyẹwò dáadáa kí ọ sí mó irú owó tí ìjọba ti tẹlẹ fi sinu akoto ìjọba bi bee kọ, oun ati awọn osise yoo pada gbena wo oju ara wọn''.

Ìyà yìí pọ̀jù

Suleiman Akingbolu tó jẹ́ oṣiṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ ní ìlú Ekiti ni kò bá dá ti Fáyẹmí ba le mú ìlérí yí ṣé nítorí ará n ní àwọn oṣiṣẹ.

O ni ''ko yẹ ki awọn olosẹlu maa ka sisan owo osu gẹgẹ bi aseyori nitori ẹ̀tọ́ ni ki wọn gba owo lẹyin isẹ.''

Nígbà tí BBC béèrè pé báwo ní ìgbé ayé tí ṣe rọrùn laigba owó oṣù, Suleiman ní ìpeníjà nlá ní eyi jẹ fun awọn oṣiṣẹ.

Àkọlé àwòrán,

Ìpínlè Èkìtì wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí o n gba owó tó kéré jù láti ọdọ ìjọba àpapọ̀

''Nnkán rọrùn díẹ fún àwa ti a n ṣé iṣẹ àgbẹ diẹdiẹ ṣugbọn fún àwọn tí kò ní ọnà míràn ìnira nlá ní àìrí owó oṣù gbà je''

Ìwádìí ilé iṣé BBC ṣé àfihàn pé oṣù kẹwa ọdún tó kọjá ní Gómìnà Fayoṣe san owó oṣù oṣiṣẹ ijoba ibile àti àwọn olùkọ kẹyìn.

Ni ti awọn oṣiṣẹ ìjọba ìpínlè àti olùkọ ilé ẹkọ gírámà, Oṣù kíni ọdún yi ni wọn gbà owó oṣù kẹyìn.