Khadijat Oluboyo: Ilé ẹjọ́ sọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sí gbaga

Olólùfẹ́ ti wọ́n ló pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ fi ṣòògùn ní Akurẹ fojú ba ilé ẹjọ́.

Ilẹ ẹjọ kan nilu Akure ti paṣẹ ki arakunrin Adeyemi Alao ti wọn fẹsun kan pe o pa Khadijat ọmọ igbakeji gomina Ipinlẹ Ondo nigba kan ri, Alhaji Lasisi Oluboyo, lọ rọọkun naa lẹwọn.

Ọjọ Aje ni wọn gbe Adeyemi lọ ile ẹjọ kekere to wa ni Oke Eda, Akure, lori ẹsun pe o gbèrò lati pa Khadijat pẹlu awọn afurasi miran ti wọn ti fẹsẹ fẹ.Adajọ Victoria Bob-Manuel to gbọ ẹjọ naa sọ pe ile ẹjọ oun kò lagbara lati gbọ ẹjọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Ọlọ́pàá Ondo bá òkú ọmọ igbákeji gómínà tẹ́lẹ̀rí nílé Adeyemi Alao

Fun idi eyi, o ni ki Adeyemi lọ rọọkun lẹwon titi ti ẹka to n ri si ipẹjo (DPP) yoo fi gba ile ẹjọ ni imọran lori ọrọ naa.

Nílé ẹjọ́ ní Akurẹ

Adajo ni ki wọn gbe Adeyemi pada siwaju ile ẹjọ ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu to m bọ.Nigba ti awọn ọlọpaa gbe Adeyemi de ile ẹjọ, ṣe ni ero ya bo yara igbẹjọ lati wo afurasi naa.Sugbon ko si awọn ẹbi Khadijat kankan nibi igbẹjọ naa.

Bi a ko ba gbagbe Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n ti ń wá Khadijat tó jẹ́ ọmọ igbákeji gómínà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Ondo,ni wọ́n bá òkú rẹ̀ ní ilé àfẹ́sọ́nà rẹ̀, Adeyemi Alao.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ni awọn ṣi n wa awọn afunrasi to ku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: