Ẹ̀kùn omi Katsina: Omi gbé òpó àti ọmọ mẹ́ta lọ

Awọn to lugbadi omiyale

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé wọ́pọ̀ l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà lásìkò òjò. Ó tí wáye ní ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ogun ati Eko nàá.

Awọn olugbe ilu Jabiya nipinlẹ̀ Katsina, ṣi n ka ofo wọn lori iṣẹlẹ omiyale to waye nibẹ.

Ọpọlọpọ ile lo ṣi wa ninu ibanujẹ ti iṣẹlẹ ojo arọọrọda naa mu ba ẹbi wọn.

Bakan naa ni isẹlẹ ẹkun omi yii tun mu ẹmi ọmọ osu mẹta lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Baba Khadijat Oluboyo jẹ́rìí ọmọ rẹ̀

Baba ọmọ naa, to ba BBC sọrọ salaye pe, idunnu ṣubu lu ayọ fun oun nigba ti iyawo oun bimọ yii, nitori pe oun ni akọbi wọn, ṣugbọn o jẹ nkan ibanujẹ pe omi gbe e lọ.

Ohun to tun ba ni lọkan jẹ nipe ko ni aworan ọmọ naa, nitori aworan kan ṣoṣo to ya wa lori ẹrọ ibanisọrọ t'omi gbe lọ.

Ohun kan to n tu u ninu nipe, iyawo rẹ wa laye, awọn mejeeji si nireti pe wọn yoo bimọ mii.

Obinrin opo kan ku pẹlu ọmọ mẹta

Isẹlẹ ẹkun omi yii tun da họu-họu silẹ ninu ile kan nigba to gbe opo kan ati ọmọ rẹ mẹta lọ.

Awọn aladugbo obinrin naa sọ fun BBC pe ọdun to kọja ni ọkọ obinrin naa ku, oun atawọn ọmọ rẹ mẹta lo si n gbe ninu ile naa.

Wọn ni lasiko ti ẹ̀kun omi naa n pọ si, ni awọn ara adugbo to ti raaye gun ibi to ga n gbọ igbe ẹ gbami lẹnu obinrin naa atawọn ọmọ rẹ.

Eyi lo mu ki wọn so okun mọ igi kan, ti wọn si ju okun naa si lati lo fi gun igi, sugbọn agbara omi naa mu ki o ṣoro fun lati fa ogun naa.

Bi omi ṣe gbe lọ ọ pẹlu ọmọ mẹrin ni yii.

Ẹyin ọ rẹyin ni wọn ri oku wọn, ti wọn si ti sin wọn.

Agbegbe ibi ti omiyale naa ti ṣọṣẹ

Àkọlé àwòrán,

Àwòrán atọ́ka àwọn ìlú tó wà ní Katsina

Iyawo ọsingin ba omiyale lọ

Ọjọ Ẹti to kọja ni awọn ara adugbo sọ pe ọmọbinrin naa ṣe igbeyawo, ko to dipe wọn gbe e wa sile ọkọ rẹ lọjọ Abamẹta.

Ọjọ Aiku, ti i ṣe ọjọ keji ni ojo naa bẹrẹ.

Oun naa wa lara awọn ti omi gbe lọ, to si gba ibẹ di ero ọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyíì tí omíyalé yòó ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà

Awọn eniyan ṣi pọ babi ni ile iwe alakọbẹrẹ ilu Jibiya, ti wọn lo gẹgẹ bi ibudo ifiniwọ si, sugbọn awọn eniyan naa n kun pe awọn ko ri ounjẹ ati awọn nkan amaye dẹrun mi i gba.

Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe, iṣẹlẹ omiyale naa to waye ni ipinlẹ Katsina dun oun pupọ.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ naa, Aminu Masari sọ fun awọn oniroyin pe o to eniyan mẹrinlelogoji to padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ naa.

Àgbàrá omíyalé ba ilé 500 jẹ́ ní Nàìjíríà

Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ile lo ti lugbadi iṣẹlẹ omiyale to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Katsina.

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ìsẹlẹ omiyale to waye ni Katsina yii ba oun lọkan jẹ pupọ.

Gomina ipinlẹ naa, Aminu Masari to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ f'awọn oniroyin ni ko din ni eniyan mẹrinlelogoji to padanu ẹmi wọn sinu i'sẹlẹ yii, ti ogun eniyan o si tii jẹ rírí ni ìlú Jibia, ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ogunlọgọ eniyan lo ti di alainile lori l'awọn ilu bi Tundun Takari, Dan Tudu, Unguwar kwakwa, Unguwar Mai Kwari, atawọn mii ni ipinlẹ Katsina.

Oluranlọwọ pataki fun Buhari lori eto iroyin ati ipolongo, Garba Shehu sọ pe ààrẹ ti pasẹ fun awọn alaṣẹ lati pese iranlọwọ fun awọn ti ọrọ kan.

Ojo arọọrọ da naa bẹrẹ ni alẹ ọjọ Aiku, to si rọ titi di ọjọ keji.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀nà ọ̀fun lọ̀nà ọ̀run - omi ò jẹ́ ká ta ọjà

Olórí ìlú Jibia, Alhaji Rabe Rabi'u, ni ohun ko ti i ri iru ojo bẹ ẹ ri laye oun, ati pe o da a loju pe ọtalerugba maalu lo ku nitori iṣẹlẹ naa, ti ọpọlọpọ oko si di bibajẹ.

Akọwe agba fun ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Katsina, Dokita Aminu Waziri, ni awọn ti bẹrẹ si ni san gbogbo ọna lati ṣawari awọn to di awati.

Bakan naa lo ni, awsn ti n wa ile ifiniwọ si fun awọn ti omiyale naa ti ss di alainile lori.