Àgbàrá omíyalé Katsina ru ìyàwó mi lọ si orílẹ̀-èdè Niger

Àkọlé fídíò,

È gbọ òun ti ojú awọn ara ipinle Ogun rí lọwọ ìṣẹlẹ omiyale

Nǹkan kò rọgbọ fún àwọn tí ọ farakaaṣa omíyalé to sẹlẹ laipẹ yi láwọn ìpínlè mẹta lorílè-èdè Nàìjíríà.

Ọpọ ile àti nnkán ìní ló ṣofo nínú ìjàmbá omí yalé naa tó wáyé ní Katsina,Ogun ati Ondo.

Nígbà tí BBC Yoruba ṣe àbẹwò sí àwọn agbègbè tí ìṣẹlẹ náà kàn ni ipinle Ogun ati Katsina n'isẹ ní àwọn ará àdúgbò n bá ará wọn kẹdun.

Ládugbó Oke Sokori, alàgbà James Oluyinka Okebujola di ẹbí ìṣẹlẹ náà rú ìjọba.

''Wọn ko la ojú ọnà tí omi le gbà lo se okunfa ìjàmbá yí''

Ṣugbọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun Ibikunle Amosun ní aitele ìlànà tó dé ilé kíkọ lo ṣokunfa ìṣẹlẹ náà.

Àkọlé àwòrán,

Gomina Ibikunle Amosun ko awọn alase ijoba sodi lo si awọn agbegbe ti isẹle naa kan.

Nigba tí o ṣé àbẹwò sí àgbègbè tí ìṣẹlẹ náà kàn Gomina Amosun ro àwọn ará ìlú láti ye ma ko ilé sójú ònà ti omi n gbà.

Sugbọn awọn ara ipinle Ogun nikan ko ni ìṣẹlẹ náà kàn.

Ogunlọgọ eniyan lo ti di alainile lori ni agbegbe Jibiya nipinle Katsina latari ìṣẹlẹ omíyalé ọjọ Aiku

Oun ti oju wọn ri o kọja afẹnusọ.

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti sin oku iyawo Sani ti omiyale gbe lo

Sani Yahaya to padanu ẹmi iyawo rẹ so fun BBC pe orileede Niger lawọn ti ri oku rẹ nibi ti omi gbe lọ.

Ilu Sani sun mo Madarumfa ti o wa ni orileede Niger .

"Ori ibusun ni iyawo mi wa nigba ti omiyale naa bẹrẹ laago mọkanla alẹ''

"Bi mo ti se n sapa lati di nnkan mu ni omi naa gbe lo.Leyin ti mo ribi bọ labere si ni wa.Ọjọ keji la to ri oku rẹni Madarumfa nibi ti ẹrọfọ ti bo mọle.''

O kere tan eeyan ogoji la gbo pe o ku ninu isele naa ni ipinle Katsina.

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ile àti nnkán ìní ló ṣòfò nínú ìjàmbá omíyalé naa

Bakannaa ni ọpọlọpọ ilé ìgbé to wa lagbegbe Totoro ni Ipinle Ogun ní o farakasa ìṣẹlẹ náà ti omi sí gbé òpó ọkọ ayọkẹlẹ lọ.

Ìkọ BBC Yoruba rí àwọn oṣiṣẹ pajawiri ipinle Ogun ti wọn n tiraka lati kò àwọn nnkán to bajẹ kúrò nínú omí.

Ládugbó Amolaso, òpó ilé ìgbé lo wọ omí nígbà tí afárá kan ti wọn ṣẹṣẹ parí láì pé yí na já lulẹ̀.