Yíyan olùdíje gómìnà ń dá wàhálà sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC l'Ọ́ṣun

Awọn oludibo n dibo
Àkọlé àwòrán Olubadamọran fun ẹgbẹ oṣelu APC lo kede rẹ fun awọn oniroyin pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu yọ alaga ati akọwe ẹgbẹ ọhun

Oniruuru awuyewuye lo ti n wọ tọ eto ati dibo yan oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun.

Ohun to n da awuyewuye silẹ naa ni ipinnu awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lati lo eto idibo oju koro ninu eyi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ kaakiri wọọdu idibo nipinlẹ naa yoo ti dibo fun yiyan oludije ẹgbẹ oṣelu naa dipo ti aṣoju ti wọn n lo tẹlẹ.

Yatọ si pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn oludije ti wọn koro oju si eyi, awọn eeyan kan laarin igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu naa yọ alaga ẹgbẹ oṣelu naa, ọgbẹni Gboyega Famodun ati akọwe ẹgbẹ, Rasak Salinsile.

Olubadamọran fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lori ọrọ ofin, amofin Goke Ogunsọla lo kede rẹ fun awọn oniroyin pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu naa lo yọ alaga ati akọwe ẹgbẹ ọhun.

"A ti dibo inu wa ko dun si ọ ranṣẹ si alaga ati akọwe ẹgbẹ yii. Ẹsun wọn si ni pe wọn lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa lati kan eto idibo ojukoro ni didan fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa eleyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ ko dunu si."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Rasak Salinsile ṣalaye pe ere'mọde lasan ni igbesẹ naa.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe ọna ati dena lilo owo fi ra ibo ni igbesẹ ti awọn adari ẹgbẹ gbe lati lo eto idibo oju koro ninu eyi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ yoo ti funra wọn yan ẹni ti wọn fẹ.

"Awọn ọmọ ẹgbẹ la fẹ ko funrawọn yan ẹni ti wọn fẹ. Lọtẹ yii a ko fẹ ki awọn baba olowo o lo owo fi ra iwọnba perete aṣoju tẹlẹ. Ko si wahala laarin ẹgbẹ ṣugbọn awọn kọlọransi lo n pariwo lori rẹ."

Àkọlé àwòrán APC fẹ lo eto idibo oju koro ninu eyi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ kọọkan yoo dibo yan oludije dipo ti aṣoju ti wọn n lo tẹlẹ

Ohun ti pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ n beere fun naa ni eto idibo awọn aṣoju (Delegate system)

Bi eyi ti n lọ lọwọ lawọn igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu naa tun pariwo 'ko si giri'

Amọṣa bayii, ọrọ tun ti ba ibomiran yọ pẹlu bi awọn oludije mejila to wa lati ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Ọṣun ti pariwo pe ohun ti awọn n fẹ naa ni eto idibo aṣoju ti o wa nilẹ tẹlẹ.

Ohun ti wọn n sọ ni pe awọn eeyan kan ngbero fi eto naa ṣe arumọjẹ ni wọn fi n pe fun eto idibo gbogbo ọmọ ẹgbẹ dipo ti aṣoju.