Nigeria Air: Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú tuntun ṣí'wọ́ iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad
Ijọba Naijiria sọ nigba ti wọn kede idasilẹ ileeṣẹ naa pe ojú ọnà mọ́kànlélọ́gọ́rin ni ọkọ òfurufú náà yóò ma rin
Mínístà fún ètò ìrìnàjò ọkọ̀ òfurufú Hadi Sirika ti kẹde pe wọn ti so ileesẹ ọkọ ofurufu Naijiria tuntun, Nigeria Air rọ bayi.
O sọ lori Twitter ni Ọjọru pe igbimọ apapọ orilẹede Naijiria lo ṣe ipinnu naa lati so ileeṣẹ naa rọ. Ko sọ igba ti wọn yoo yi ipinnu naa pada.
Ẹ o ranti wipe nigba ti wọn ṣe ikede idasile ileeṣẹ naa, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹhinti, ẹka ti Nigeria Airways sọ fun BBC pee awọn ko ni jẹ ko ṣiṣẹ ti wọn ko ba san owo ajẹsilẹ awọn
Alaga ẹgbẹ naa, Sam Ezene ni iyalẹnu lo jẹ fun oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ nigba ti wọn gbọ pe ijọba kede ileeṣẹ ọkọ ofurufu tuntun, pe ko yẹ ki ijọba Naijiria da ileeṣẹ mi i silẹ nigba ti wọn ṣi n jẹ awọn oṣiṣẹ fẹhinti ni owo ọdun mẹrinla
O ni 'O yẹ ki wọn yanju owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ to n ba ileeṣẹ ọkọ ofurufu akọkọ, Nigeria Airways, to kogba wọle naa ṣiṣẹ.''
O ni itiju lo jẹ fun Naijiria, bi ijọba ṣe lọ sẹ ikojade ileeṣẹ tuntun naa ni orilẹede England.
Ìgbésẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì
Bakan naa ni Ọgbẹni Ezene ni, awọn ti kọ lẹta si minisita fun igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria, Hadi Sirika, pe ileeṣẹ tuntun Nigeria Air ko ni bẹrẹ iṣẹ, ayafi ti wọn ba san owo awọn to to biliọnu mejidinlọgọrin Naira.
O ni eyi yoo ṣeeṣe fun awọn nitori pe 'akọṣẹmọṣẹ ninu imọ nipa igbokegbodo ọkọ ofurufu ni gbogbo awọn.''
Ijọba ti kọ kede pe wọn yoo san owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ fẹhinti naa ninu ọdun yii, amọ ti wọn ko ti i ri i gba titi di asiko yii.
Ijọba ti kọ kede pe wọn yoo san owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ fẹhinti naa ninu ọdun yii, amọ ti wọn ko ti i ri i gba titi di asiko yii
Ṣaaju ni ijọba Naijiria ṣe ikojade ileeṣẹ ọkọ ofurufu tuntun l'Ọjsru l'orilẹede England, lati fi rọpo meji to ti wa nigba kan ri, Nigeria Airways ati Air Nigeria .
Eero awọn ọmọ Naijiria ṣọtọọtọ lori orukọ ti wọn fun ileeṣẹ tuntun naa. Bi awọn kan ṣe n dunnu pe iru rẹ waye, ni awọn kan n yọ ṣuti ete si i.
Babatunde E. Aideloje sọ loju opo Facebook BBC Yoruba pe ''Kilode ti won o fi pada tunsọ ni "Nigeria Airways" eyi ti n se orukọ ti wọn n jẹ tẹlẹ tẹlẹ?
Igbesẹ naa i ba dara pupọ. Sugbọn sa orukọ titun wọn yii ko fi bẹ yẹn dara.''
Ṣugbọn ni eero Bello Taoheed Ọlawale "Orukọ tuntun yii naa rẹwa. O da gẹgẹ bii Egyptian air. Mo fẹran amin tuntun ti wọn fun un bayii."
Ìjọba Nàìjíríà tí kéde orúkọ tuntun fún ọkọ̀ òfurufú orílèèdè náà tí wọ́n fẹ́ ṣe àjínde rẹ̀.
'Nigeria Air' ni orúkọ ti wọn yan fún un.
Ojú òpó Twitter ilé iṣẹ ìjọba Naijirià ní wọn fí ìkéde náà sì lọ́jọ́rú ọ̀sẹ̀.
Mínístà fún ètò ìrìnà òfurufú Naijiria, ọgbẹni Hadi Sirika ti sáájú fí ọrọ síta láti kí àwọn èèyàn Naijirià ku ojú lọnà àjínde ọkọ̀ òfurufú orílè-èdè Nàìjíríà.
Nigba ti o n sọrọ níbi ayẹyẹ igboruko tuntun ọkọ òfurufú náà jáde níbi ayẹyẹ àfihàn ọkọ òfurufú to n wáyé ni Farnborough, Hadi sọ pé ìṣẹlẹ manigbagbe ni igboruko jade náà jẹ.
O tẹ̀síwájú pé ìdá marun-un nínú ọgọrùn ní ìjọba yóò ní nínú ilé iṣẹ ọkọ òfurufú náà àti pé ìjọba yóò yọwọ kúrò nínú iṣẹ àkóso ọkọ òfurufú náà.
Oríṣun àwòrán, @FAAN_Official
Hadi so pé ìṣẹlẹ manigbagbe ni igboruko jade náà jẹ.
Ọdún 1958 ni wọn dá ọkọ̀ òfurufú Nigeria Airways silẹ̀ ṣugbọn o ko 'gba si ile lọdun 2013.
Ọpọ ọmọ Naijirià lo ti n jaran àjínde ọkọ òfurufú ti orílẹ̀èdè Naijiria.