Ekiti Election: Gómìnà tí wọn sẹ̀sẹ̀ dìbò yàn gbàwé ẹ̀rí

Kayode Fayemi ati Bisi Ẹgbẹyẹmi
Àkọlé àwòrán Oriko INEC to wa ni popona Iyin tuntun to wa ni ilu Ado-Ekiti ni o ti tgba iwe ẹri naa pẹlu igbakeji rẹ, Oloye Bisi Egbeyemi,

Kayode Fayemi to jawe olubori ninu idibo gomina Ipinlẹ Ekiti ti wọn ṣẹṣẹ ṣe tan, ti gba iwe ẹri iyansipo rẹ lati ọwọ ajọ INEC.

Ilesẹ ajọ INEC to wa ni popona Iyin tuntun ni ilu Ado-Ekiti ni o ti gba iwe ẹri naa pẹlu igbakeji rẹ, Oloye Bisi Egbeyemi,

Fayemi to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, lo jawe olu bori ninu idibo gomina naa to waye ni ọjọ Abamẹta to kọja, ti oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọjọgbọ́n Kolapo Olusola-Eleka si gbe ipo keji.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: